Ọlawale Ajao, Ibadan
Iwọde ti awọn ọdọ n ṣe kaakiri ilu Ibadan, nitori iṣoro ọwọngogo owo Naira ti ṣakoba fun eto iponlongo idibo oludije fun ipo aarẹ orile-ede yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi nilẹ Yoruba.Kinni ọhun pa gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, paapaa lara ninu eto ipolongo idibo tirẹ naa.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, ni Peter Obi pinnu lati ba igbimọ to n ṣakitiyan lori idagbasoke ẹkun Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii, iyẹn South-West Development Stakeholders Forum (SDDSF) lalejo ni gbọngan Jogor Centre, to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Ipade ọhun ni iba jẹ anfaani fun Obi lati polongo idibo rẹ fun gbogbo ọmọ Yoruba gẹgẹ bi igbimọ SWDSF ṣe gbe eto naa kalẹ fun gbogbo awọn to n dupo aarẹ lati waa sọ ipinnu wọn fun gbogbo ọmọ Kaaarọ-o-o-ji-ire-bi atawọn oniroyin gbogbo ti wọn yoo fọnrere ọrọ to ba sọ nibẹ fun gbogbo aye gbọ.
Lara awọn oludije dupo aarẹ ilẹ yii ti igbimọ naa ti ṣe bẹẹ gba lalejo ṣaaju ni Alhaji Atiku Abubakar (PDP); Ọmọyẹle Ṣoworẹ (AAC), Kọla Abiọla (PRP) Ati Ọmọọba Adebayọ Adewọle (SDP).
Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju aago mẹwaa aarọ ti wọn fi eto yii si ni gbọngan ọhun ti kun fun ero rẹpẹtẹ, ti baaluu to gbe Peter Obi paapaa wa s’Ibadan ti balẹ sibi kan ti ko jinna si Jogor Centre, ṣugbọn oju lasan ni wọn fi ri oludupo aarẹ naa, ọkunrin yii ko to ẹru to n sọ kalẹ ninu baalu to gbe e wa debi ti yoo de inu gbọngan nla ti wọn ti n duro de e naa.
Funra alaga igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, Ọgbẹni Alao Adedayọ, lo sọ pe ki awọn ero to n duro de e maa lọ sile wọn nigba to ti daju pe ọkunrin oloṣelu naa ko le sọkalẹ wa sibẹ nitori gbogbo rogbodiyan ifẹhonu han to n lọ.
Nigba to n kede isunsiwaju eto naa, Alaga igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to tun jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE, sọ pe “mo ki gbogbo wa patapata. Peter Obi ti wa, o wa sibi lati waa ba yin sọrọ. Ṣugbọn nnkan to ṣẹlẹ laarin ilu, ti wọn n fẹhonu han, ti wọn n sun taya, awọn alaabo sọ fun un pe o ṣee ṣe ki kinni yii le ju bayii lọ ti wọn ba ri i.
“Oun naa pe wa, o ni ṣe ibi yii séèfù fun oun lati wa, awa naa waa ṣalaye pe Ọlọrun o ni i jẹ ka ri ko-ṣe-daadaa, ti nnkan kan ba ṣẹlẹ, awọn eeyan kan aa sọ pe nilẹ Yoruba ni wọn ti kọ lu Peter Obi, pe wọn mọ-ọn-mọ ṣe e ni.
“Iyẹn lawa naa fi waa sọ pe o daa, ti aisi eto aabo to wa niluu ko ba faaye gba a, ko maa lọ, to ba di ọjọ mi-in, a o tun maa pe e.
‘‘Mo tun wa n fi asiko yii sọ fun yin gẹgẹ bi mo ṣe maa n sọ pe eto ta a gbe kalẹ yii, ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu kankan lo ṣonigbọwọ wa, ki i ṣawọn olowo kan lo ṣonigbọwọ ẹ, awa ọmọ Yoruba ta a nigbagbọ pe awọn to fẹẹ dupo aarẹ ni Naijiria, a lẹtọọ lati ri wọn, ẹyin araalu lẹtọọ lati ba wọn sọrọ lo ṣagbatẹru eto yii. Iyẹn lẹ o ṣe ri i ka pe awọn ọba atawọn olowo sibi eto yii.
‘‘A fẹ kẹ ẹ ri awọn to n dupo aarẹ, ki awọn naa ri yin, kẹ ẹ si jọ sọrọ. Nitori ẹ la ṣe gbe eto yii kalẹ. A o gbowo kankan lọwọ oloṣelu kankan, a o si reti owo kankan lọwọ wọn. Nitori ẹ la ṣe le sọ fun yin pe kẹ ẹ maa lọ sile yin.
“Nnkan jijẹ ta a maa n fun yin nibi eto yii ṣi wa o, wọn maa too gbe ounjẹ naa de laipẹ, ẹni to ba le duro jẹ ẹ, ko duro jẹ ẹ, ẹni ti ko ba le duro jẹ ẹ, ko maa gbe e lọ sile. Ẹ seun”.
Rogbodiyan to n lọ lọwọ nigboro Ibadan yii naa lo jẹ ki Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, da eto ipolongo idibo to n ṣe kaakiri awọn ijọba ibilẹ gbogbo nipinlẹ naa duro digba ti alaafia yoo fi jọba, nitori ko sẹni to mọ ọwọ to ṣee ṣe ki awọn janduku to wa laarin awọn oluwọde naa gbe nigba ti wọn ba foju kan oludije dupo oṣelu tabi eeyan to wa lori aleefa ijọba.