Iwọde lori owo tuntun: Ṣọja yinbọn pa ọlọkada n’Ibadan

Faith Adebọla

 Iwọde ati ifẹhonuhan to n waye niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, latari inira ti pipaarọ owo Naira atijọ si tuntun, ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to gogo si i lasiko yii ti gba ọna mi-in yọ, awọn ṣọja ti lọọ ya lu awọn oluwọde naa l’Apata, niluu Ibadan, wọn ṣina ibọn bolẹ nibẹ, ibọn naa si gbẹmi ọlọkada kan loju-ẹsẹ, lọrọ ba di iṣu-ata-yan-an-yan-an.

Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keji yii, lawọn ọdọ tinu n bi, atawọn onimọto, ti bẹrẹ iwọde wọọrọwọ niluu Ibadan, adugbo Iwo Road, lawọn ọdọ yii kora wọn jọ si, ti wọn si di oju ọna ti gbogbo awọn arinrin-ajo maa n gba naa pa.

Eyi ti mu inira ba awọn arainrin-ajo to n gba awọn agbegbe naa kọja, niṣe ni gbogbo ọkọ duro, nitori ko si bi wọn ṣe le kọja pẹlu bi wọn ṣe di ọna pa.

Nigba ti yoo fi di ọsan ọjọ naa, iwọde naa ti bẹrẹ si i lagbara, latari bawọn ọlọpaa ko ṣe le da awọn ọdọ naa duro, nigba ti wọn yoo si fi ko ifẹhonuhan wọn de sẹkiteria ijọba ipinlẹ Ọyọ, ọrọ ọhun ti kọja wẹrẹwẹrẹ, wọn se geeti olu ileeṣẹ ijọba pa, wọn sọko ba awọn gilaasi ọkọ atawọn nnkan ẹṣọ ọgba naa, wọn bi wọn ṣe n ju igi, ni wọn n da yeepẹ, ti wọn wọn n kọrin owe ati ija, pẹlu oriṣiiriṣii akọle lọwọ wọn.

ALAROYE gbọ pe wọn ṣe ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọfiisi gomina leṣe, bẹẹ ni si ba ọfiisi gomina jẹ. Apa awọn agbofinro ko ka awọn ọdọ naa, eyi to mu ki wọn ti geeti to wọ inu ileesẹ ijọba naa pa.

Oriṣiiriṣii akọle ni awọn ọdọ naa gbe dani, ti wọn si n kọrin lọlọkan-o-jọkan. Lara ohun ti wọn kọ sara akọle naa ni: ‘Buhari, iya yii pọ’, ‘ko sowo, ko si epo, ṣe ẹ fẹẹ pa wa ni’ ijọba Buhari, wa nnkan ṣe sọrọ to wa nilẹ yii’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni wọn n gbe kiri.

Lọjọ keji, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide yii, lati owurọ lawọn oluwọde naa ti tun kora jọ, wọn si pọ ju awọn ti ọjọ Furaidee lọ, amọ ki wọn too de ibi iwọde naa lawọn ṣọja kogberegbe ti lọọ tẹlẹ de wọn, pẹlu awọn ọlọpaa atawọn agbofinro mi-in.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ fun iweeroyin Tribune pe “awọn oluwọde naa ko ba tija wa, bi wọn ṣe n rọ girọgirọ lọọ sagbegbe Apata, n’Ibadan, lojiji, lairotẹlẹ lawọn ṣọja bẹrẹ si i yinbọn ni kọṣẹkọṣẹ, eyi si da jinni-jinni bo awọn oluwọde atawọn araalu, kaluku sa asala fẹmii ẹ, awọn kan dubulẹ sẹgbẹẹ titi, awọn kan sa sinu gọta, ki ọta ibọn to n fo lau lau kiri ma lọọ ṣeeṣi ba wọn.

Amọ nigba ti idarudapọ naa yoo fi rọlẹ, ibọn ti ba awọn kan, wọn ri ẹni kan to ti ku, awọn to mọ ọn sọ pe ọlọkada lọkunrin naa, awọn kan si n gba itọju lọwọ ileewosan Lafia, to wa lagbegbe NNPC, n’Ibadan, obinrin wa ninu wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹsọ, ko ti i fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, amọ awọn oluṣewọde naa ti tu ka, awọn agbofinro si ti wa kaakiri awọn ikorita atawọn ẹka ileeṣẹ ọba lati pese aabo, bo tilẹ jẹ pe niṣe lawọn eeyan n rin tifura tifura lawọn agbegbe tiwọde naa ti waye.

Leave a Reply