Iwọde ‘Oodua Nation’ yoo waye niluu Eko ni Satide-Sunday Igboho

Faith Adebọla

Ajigbagbara ọmọ Yoruba tawọn ọtẹlẹmuyẹ lọ sile rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Oloye Sunday Igboho, ti sọ pe Yẹkinni kan ko ni i yẹ iwọde fun ‘Oodua Nation’ to yẹ ko waye niluu Eko ni Satide, ọjọ kẹta, oṣu keje yii. O ni iwọde naa yoo lọ bi awọn ti ṣe pinnu rẹ.

Igboho to gbẹnu akọwe iroyin rẹ, Ọlayẹmi Koiki, sọrọ sọ pe iwọde naa yoo waye, bẹẹ ni Sunday Igboho yoo si tun pada wa bii akọni.

Koiki ni ki awọn eeyan gbagbe ahesọ ti awọn kan n sọ kiri pe iwọde naa ko ni i waye. O ṣalaye ninu fidio kan to fi si ori ẹrọ ayelujara pe oun ti kan si awọn ti wọn n ṣe eto naa, wọn si ti fi da oun loju pe iwọde naa yoo waye ni deede aago mẹsan-an aarọ ni Ọjọta, niluu Eko.

Koiki rọ awọn eeyan ki wọn ma ṣe jẹ ki ohun to ṣẹlẹ nile Sunday Igboho, nibi ti wọn ti paayan meji, ti wọn ba ile rẹ jẹ da omi tutu si wọn lọkan.

O ni iwọde nla ni ti ilu Eko yii yoo jẹ, wọọrọwọ ni yoo si lọ pẹlu.

Agbẹnusọ Igboho yii ni oun ti kan si Akọwe ẹgbẹ Ilana Yoruba ati Ọjọgbọn Banji Akitoye, iṣẹ si ti n lọ lati gba awọn ti wọn ti mọle silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti sọ pe iwọde kankan ko gbọdọ waye niluu Eko, to ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo jiya to ba yẹ labẹ ofin, ṣibẹ awọn eeyan naa ni dandan ni ki iwọde ‘Oodua Nation yii waye.’

Leave a Reply