Mama Abigael Ọmọjọlagbe Makinde to jẹ iya Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti jade laye laaarọ yii lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
Awọn oloṣelu atawọn ọtọkulu eeyan lawujọ ni wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun si gomina Ọyọ naa.
Ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun to kọja, ni mama naa ṣe ajọdun ọgọrin ọdun laye.
Ki Olorun Oba dari gbogbo ese ti mama se laye jiwon ki Olorun si te mama si afefe rere o Amin
Ki Olorun daabo bo awon omp ati omoomo ti mama fi sile laye o