Iya kọ lo n jẹ awọn to fọ ile ounjẹ kiri, o lohun to n ṣe wọn – Fẹmi Adeṣina 

Aderounmu Kazeem    

Fẹmi Adeṣina, oluranlọwo fun Aarẹ Muhammed Buhari nipa eto iroyin ati ohun to ni ṣe pẹlu awujọ, ti bu ẹnu atẹ lu ohun ti ajọ agbaye kan, Amnesty International sọ wi pe ebi ati bi inu ṣe n bi araalu lo mu kawọn eeyan kan maa ji ẹru ijọba ko kiri.

Adeṣina ninu ọrọ ẹ sọ pe ki i ṣe ebi tabi ibinu lo mu wọn ṣe e bi ko ṣe pe rogbodiyan to n ṣẹlẹ laarin ilu, ti ko si si ilana ofin mọ, tabi agbofinro to le bu wọn so, iyẹn lo fun awọn eeyan kan lanfaani lati huwa ọdaran ọhun.

O fi kun ọrọ ẹ pe, ajọ Amnesty International kuna patapata ninu ọrọ ti wọn sọ wi pe bi awọn ṣọja ṣe kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde ni Lẹkki lo fa sababi bi awọn ọdọ kan ṣe n ba nnkan jẹ kiri, nigba ti inu buruku bẹrẹ si bi wọn.

O ni ṣaaju ki ọrọ Lẹkki too ṣẹlẹ lawọn eeyan kan ti kọlu awọn ọlọpaa ati teṣan wọn, ti wọn sọna si teṣan ọlọpaa to wa l’Orile, l’Ekoo.  Bakan naa lo tun fi kun un pe ọgba ẹwọn to wa ni Benin ati Oko ti wọn kọlu naa, ki i ṣe ibinu kan lo n ṣe awọn eeyan bi ko ṣe pe wọn lo anfaani rogbodiyan to wa nita nigba yẹn lati fi ṣiṣẹ ibi.

 

Leave a Reply