Eeyan n wo oju, Ọlọrun n wo ọkan, lohun to ku tawọn eeyan n sọ latigba ti iroyin iku iya oṣere tiata nni, Nkechi Blessing, ti di mimọ lopin ọsẹ, nitori ọjọọbi iya naa ni ọmọ rẹ n palẹmọ lọwọ, afi bi iku ṣe wọle wẹrẹ to mu iya lọ lojiji.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an yii, ni Toyin Abraham toun naa jẹ oṣere tiata, kede ipapoda Iya Nkechi loju opo Instagraamu rẹ, to si ni kawọn eeyan maa gbadura fun oṣere naa nitori ohun to ṣẹlẹ si i.
Ṣe ko kuku sẹni to mọ pe iku ojiji yoo pa Iya Nkechi, ipalẹmọ ọjọọbi iya naa ati aburo Nkechi to n jẹ Jennifer Ijeoma Sunday, ni wọn n ṣe lọwọ. Koda, nitori ọjọọbi awọn mejeeji naa ni Nkechi ṣe wa siluu Eko, to ba iya rẹ ati aburo rẹ pẹlu ọmọ oṣere naa ya fọto, to si kọ akọle sibẹ pe oun ti de s’Ekoo lati ba awọn ọlọjọọbi ya fọto, iyẹn iya rẹ ati aburo rẹ.
Nkechi kọ ọ sibẹ pe ọjọ kejidinlọgbọn, ati ikọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an yii, ni ọjọọbi awọn mejeeji.
Afi bi iya ti Nkechi n palẹ ọjọọbi mọ fun ṣe ku ki ọjọọbi naa too de, ti ibanikẹdun ati ọfọ si rọpo ọjọọbi ti oṣere ọmọ Ibo to n ṣere Yoruba naa fẹẹ ṣe fun iya rẹ.
Latigba ti ọfọ naa ti ṣẹ Nkechi lawọn eeyan ti n ba a kẹdun, ti wọn n rọ ọ pe ko mọkan, nitori ko si kinni kan teeyan le ṣe bi iru eyi ba waye, afi ki tọhun gba f’Ọlọrun.