Iya tawọn Fulani yinbọn fun n’Ijẹbu-Oru ti ku o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣe ẹ ranti iya kan, Moronkeji Salami, tawọn Fulani yinbọn fun ni àgbọ̀n, ti wọn tun ṣa ladaa kaakiri ara lasiko to n lọ soko ẹ lọna Ijẹbu-Oru ninu oṣu kin-in-ni, ọdun yii, iya naa ti ku o.

Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji yii, ni obinrin naa ti apapọ orukọ ẹ n jẹ Muslimọt Abẹni Moronkeji Salami, jade laye lẹyin gbogbo inawo ati inira to ti jẹ latari wahala to ṣẹlẹ si i naa. Ọjọ keji rẹ ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, ni wọn si in nilana Islam.

Iwe alẹsode ti wọn fi kede isinku iya naa fidi iku rẹ mulẹ, bẹẹ lawọn to sun mọ idile naa ṣeyẹ ikẹyin fun oloogbe, nipa lilọwọ si isinku alafẹ obinrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin(66) naa.

Tẹ o ba gbagbe, inu mọto ni Abẹni wa lọjọ ti ikọlu naa waye, saiti rẹ to ti n ṣiṣẹ lọwọ lo n lọ lọna Idofẹ. Ibi kan ti wọn n pe ni Quarry lo de, lọna Ijẹbu-Oru, lọjọ naa, tawọn Fulani ti wọn to mẹjọ fi yọju si i lojiji lati inu igbo, wọn n da maaluu bọ niwaju rẹ.

Awọn maaluu yii pọ gidi gẹgẹ bi ọmọ iya yii ṣe ṣalaye, bẹẹ ni tija-tija ni wọn n bọ lọdọ iya to n lọ jẹẹjẹ ẹ naa.

Bi Moronkeji ṣe ri wọn lo fẹẹ sare pada, ṣugbọn wọn bo o, wọn si yinbọn si taya mọto rẹ mẹrẹẹrin, wọn jo o. Iya naa n bẹ wọn pe ki wọn ṣaanu oun, ṣugbọn wọn ko dahun, wọn yinbọn fun n lagbọn, wọn yinbọn fun un lọwọ to jẹ niṣe ni ika atanpako osi rẹ ge danu.

Aṣe awọn Fulani naa ko ti i ṣetan pẹlu Abẹni, niṣe ni wọn tun yọ ada ti i, ti wọn ṣa a kaakiri ara.

Nigba ti wọn ṣe bẹẹ tan, wọn n ti i nibi to sọrikọ si niwaju mọto rẹ lati mọ boya o ti ku patapata, bẹẹ ni wọn n pe e ni madaamu, madaamu, wọn fẹẹ mọ boya o ti ku patapata tabi ẹmi ṣi wa lara rẹ.

Iya naa pirọrọ fun wọn bii ẹni to ku, nigba naa lawọn Fulani yii fi i silẹ, ti wọn wọgbo lọ.

Awọn ẹlẹyinju aanu ọlọkọ to n kọja lo ṣaanu Moronkeji, wọn gbe e lọ si ọsibitu meji n’Ijẹbu, awọn iyẹn ko gba a, wọn ni o kọja agbara awọn.

Ọsibitu jẹnẹra to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, ni wọn pada gbe iya yii wa, wọn gba a nibẹ, wọn si bẹrẹ itọju fun un ki wọn too yọnda rẹ lọ sọsibitu mi-in.

Gbogbo bi wọn ṣe n gbe e kiri naa lo n gba itọju to kun fun inira lawọn ileewosan yii, ọtọ ni fidio igba ti wọn n ba a ran awọn ibi kan lara rẹ, ti iya naa n sunkun pẹlu irora, ọtọ si lasiko ti wọn di i ni bandeeji lori babatutu, ojumọ kan, itọju pẹlu inira kan ni.

Bi gbogbo eyi ṣe n lọ ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun naa n gbọ, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro wọn nipinlẹ Ogun, si ṣalaye pe awọn ti ri awọn kan mu ninu awọn to kọ lu Moronkeji, o fi atẹjade sita nigba naa, wọn si pada foju awọn tọwọ ba naa han ni Eleweeran.

Ṣugbọn oju apa ko jọ oju ara fun Moronkeji Salami mọ, gbogbo inawo-nara awọn eeyan rẹ lati ri i pe o la wahala naa ja ko seso rere.

Nigba to di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, obinrin rọgbọdọ naa dagbere faye!

Eyi lawọn eeyan to gbọ nipa iku naa kaakiri ṣe n sọ pe ogun lọrọ awọn Fulani yii, o ti kuro ni nnkan teeyan yoo kan maa fẹnu lasan royin rẹ, nitori gbogbo oṣẹ ti wọn n ṣe leeyan n ri kaakiri yii, aditi gan-an ko si le sọ pe oun ko mọ pe alaafia ko si lawujọ wa.

Ṣa, faili awọn ti wọn mu lori ikọlu iya to n jẹ Moronkeji yii yoo yipada lọdọ awọn ọlọpaa, nitori ipaniyan ti wa ninu ẹsun ti wọn yoo jẹjọ rẹ bayii, wọn yoo ni lati ṣalaye bi iṣu ṣe ku ati bi ọbẹ ṣe bẹ ẹ gan-an .

Leave a Reply