Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party, Dokita Akin Ogunbiyi, ti sọ pe gbogbo iriri ati ọgbọn inu to sọ oun di oludaṣẹsilẹ ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lorileede yii loun yoo lo lati ri i pe ipinlẹ Ọṣun di apewaawo si rere.
Nibi eto kan to waye ni Freedom Park, niluu Oṣogbo, ni Ogunbiyi ti kede erongba rẹ lati dupo gomina fun gbogbo araalu. O ni oniruuru ipenija loun ti koju lati nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin ti oun ti bẹrẹ irinajo naa.
Ogunbiyi ṣalaye pe ọmọ anibiniran loun lati ilu Ile-Ogbo, ki i ṣe owo loun nilo ti oun fi pinnu lati ṣe gomina, bi ko ṣe ifẹ otitọ ti oun ni si idagbasoke ati itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun.
O ni ohun akọkọ ti oun yoo ṣe ti oun ba di gomina ni ipesẹ iṣẹ nipasẹ eyi ti gbogbo awọn eeyan yoo fi mọ pe atẹlẹwọ ẹni ki i tan ni jẹ, ohun ti a ba ṣiṣẹ fun lo n pẹ lọwọ ẹni.
O sọ siwaju pe, “A ko gbọdọ faaye gba irọ, ariwo lasan, ẹtan ati ileri asan lati ko ba ọjọwaaju wa, a gbọdọ nigbagbọ ninuu titẹpamọṣẹ ati jijẹ olotitọ.
“Pupọ ninu awọn oloṣelu ni wọn fẹ ki agbara tubọ maa wa lapo wọn, wọn ko fẹ ẹni ti yoo yẹ wọn lọwọ wo, idi niyẹn to jẹ pe ọrọ iyapa ati ariyanjiyan ti ko lere lo mumu laya wọn.
“Iṣẹ gbogbo wa ni iṣẹ yii, a jọ maa fọwọsowọpọ lati ni iru ipinlẹ Ọṣun ti a le fi yangan lorileede Naijiria ni. Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n ṣeleri pe ni kete ti awọn ba ti dejọba ni gbogbo nnkan yoo loju, wọn mọ pe irọ ni wọn n pa, wọn fẹẹ fi ọgbọn da yeepẹ si gaari wa ni.
“Nipinlẹ Ọṣun, a ni oniruuru awọn iṣẹ-ọwọ ti a le lo lati mu ki eto ọrọ-aje wa rugọgọ si i. Ẹyin eeyan mi l’Ọṣun, gbogbo wa lo yẹ ka maa jẹgbadun gbogbo nnkan ti a ba n ri nibi, ko yẹ ko wa fun abala awọn eeyan kan.
“Ni kete ti mo ba ti de ọfiisi ni iṣẹ nla yoo bẹrẹ. Sisọ ipinlẹ Ọṣun di ibudo awọn ileeṣẹ nla nla ni afojusun iṣejọba mi. A maa fa awọn oṣere ere oriitage mọra lati fi pese iṣẹ fun awọn ọdọ wa.
“A maa da awọn okoowo ti yoo ṣi oju awọn eeyan lorileede yii ati loke-okun wa sipinlẹ Ọṣun silẹ. A maa ba awọn akọṣẹmọṣẹ dowo-pọ lori imugbooro awọn nnkan alumọni wa.
“Gẹgẹ bii agbẹ ti emi gan-an jẹ, a maa pese awọn irinṣẹ fun awọn agbẹ lati le sọ ipinlẹ Ọṣun di ibudo ounjẹ lorileede yii, gbogbo awọn eto yii lo ti wa nilẹ lai ni i si idiwọ kankan rara.”
Nibi eto naa ni ẹni to mu gẹgẹ bii igbakeji, Alhaji Kunle Jimoh, naa ti ṣeleri pe ijọba awọn oṣiṣẹ ijọba ati ti awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ni ẹgbẹ Accord Party yoo ṣe ti wọn ba le wọle gẹgẹ bii gomina l’Ọṣun.