Iyawo Buhari ti de lati Dubai, o ni diẹ lo ku ki ẹronpileeni awọn ja bọ

Iyawo Aarẹ orilẹ-ede yii, Aisha Buhari, ti de lati ilẹ Dubai to lọ o. Ọsẹ bii mẹta sẹyin ni wọn gbe obinrin naa lọ si Dubai, ti wọn ni ọrun buruku kan n dun un. Oriṣiriṣi awuyewuye lo tun jade sita lẹyin to lọ tan, nitori awọn kan fidi ẹ mule pe ki i se pe ara rẹ ko ya, o lọ si Dubai lati lọọ ra nnkan iyawo fun ọmọ rẹ ni.

Ṣugbọn lanaa ode yii, nigba ti obinrin naa de, o ni loootọ ni ara oun ko ya, itọju naa loun si ba lọ si Dubai. O dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria ti wọn gbadura foun nigba ti oun ko si nile yii, o si gba awọn dokita ti wọn ni ọsibitu nimọran pe ki wọn tun ọsibitu wọn ṣe bii ti igbalode, ti awọn eeyan ko fi ni i maa lọ siluu oyinbo fun itọju mọ.

Aisha ni nigba it awọn n bọ, Ọlọrun lo yọ awọn o, nitori diẹ lo ku ki ẹronpileeni awọn ja bọ. O ni niṣe ni atẹgun lile naa de loju ọrun, to si n fi ẹronpileeni awọn logbologbo, ṣugbọn awọn ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa ti wọn wa ẹronmpileeni naa lo gbogbo ọgbọn ati agbara wọn lati ri i pe awọn ko ja bọ, ti wọn si gbe ọkọ ofurufu naa jade ninu iji buruku to ko si. O ni oun dupẹ lọwọ wọn o, nitori bi ko si tiwọn ni, eyi ti a n wi yii kọ la ba maa wi o.

Leave a Reply