Stephen Ajagbe, Ilọrin
Iyawo Gomina Kwara, Olufọlakẹ Abdulrazaq, ti ṣetan lati ran obinrin kan, Risikatu Azeez, tọkọ rẹ, Abdulwasiu, pa ti pẹlu ọmọ meji, nitori bi awọ ẹyin-oju wọn ṣe ri lọwọ.
Obinrin naa atawọn ọmọ mejeeji ni ẹyin-oju wọn jẹ awọ omi aro (buluu), eyi to yatọ gedegbe si bi ti gbogbo eeyan ṣe ri.
Abilekọ Abdulrazaq sọ lori ikanni ibanisọrọ ori ẹrọ ayẹlujara rẹ (twitter), pe oun ti ranṣẹ pe obinrin naa lati yọju si ọọfiisi ajọ oun, Ajikẹ People Support Centre, to wa niluu Ilọrin.
Akọwe iroyin rẹ, Adeniyi Adeyinka, to fidii ọrọ naa mulẹ ni awọn n reti obinrin naa lọsẹ to n bọ. O ni ohun to ṣe pataki fawọn ni lati beere iṣẹ to fẹẹ maa ṣe ati lati wa ọna toun pẹlu ọkọ rẹ yoo fi pada maa gbe pọ lalaafia, to ba ṣee ṣe.
AKEDE AGBAYE gbọ pe aya gomina ti ba Kọmiṣanna feto ẹkọ, Sa’adatu Modibbo-Kawu, sọrọ nipa bawọn ọmọ naa yoo ṣe maa lọ sileewe ati bijọba ṣe maa ran wọn lọwọ.
Risikat Azeez ni oun atawọn ọmọ oun le riran kedere, awọ oju awọn ko fibi kan di iriran awọn lọwọ rara.
O ni bi oju oun ṣe ri niyẹn ti Wasiu fi fẹ oun, ṣugbọn ṣe lo yiwa rẹ pada nigba toun bi awọn ọmọ mejeeji, nitori bi wọn si gbe awọ ẹyin-oju oun yii waye.
Risikatu ni, “Bawọn obi mi ṣe bi mi niyẹn, emi naa si bi awọn ọmọ pẹlu ẹyin oju yii. Latigba ti wọn ti bi mi, mi o ni ipenija oju ri, mi o lọ silewosan fun itọju oju ri, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun.
“Ko sẹni to ni iru ẹyin oju yii ninu ẹbi wa; ati idile baba pẹlu ti iya. Emi ni ẹni akọkọ to maa ni i. Nigba ti mo si bẹrẹ si i bimọ, awọn naa gbe iru ẹ waye, mi o kabaamọ rara pe emi atawọn ọmọ mi ni iru ẹyin yii.”
Nigba to n sọ iha tawọn ẹbi ọkọ rẹ kọ si i, Risikatu ni, “Lẹyin ti mo bi awọn ọmọ yii pẹlu iru oju ti mo ni, ọkọ mi bẹrẹ si i ba mi ja, igba mi-in yoo jagbe mọ mi, yoo kuro nile lẹyin ọsẹ kan lo too maa pada. Ko bikita mọ nipa ohun ta a maa jẹ ninu ile, koda, awọn obi rẹ gan-an gbe lẹyin rẹ, ohun ti wọn n sọ fun un ni pe ṣe o fẹẹ tẹsiwaju lati maa bi iru awọn ọmọ to niru ẹyin-oju yii ni?
“Nigba ti wahala yii pọ ju, to jẹ pe ile awọn obi mi ni mo maa n lọ lati gba ounjẹ ta a maa jẹ ni wọn ni ki n kuro nile fun un. Latigba ti mo si ko jade, ko wẹyin wa wo debii pe yoo beere alaafia awọn ọmọ.
“O wu mi kawọn ọmọ mi kawee. Awọn obi mi gbiyanju niwọnba tagbara wọn mọ lati ran mi lọ sileewe, ṣugbọn mi o le sọ oyinbo, o maa n jẹ ẹdun ọkan fun mi. Akọbi mi ti pe ọmọ ọdun marun-un bayii, ko lọ sileewe ri latigba to ti daye. O wu mi ki wọn lọ sileewe, ki wọn si le sọ oyinbo.”