Ọlawale Ajao, Ibadan
Nibi ti ọpọ idile ti daru nitori ti ọkọ tabi iyawo n yan ale, nibẹ niyawo ile kan, Toyin Bello, ti loyun fún ọkunrin mi-in níta, ti ọkọ tó fẹ ẹ sile, Dọtun Bello, si mọ si i ṣugbọn ti wọn tun jọ n ba igbesi aye wọn lọ bii lọkọ laya.
Lẹyin eyi naa, iyawo tun pẹjọ sí kootu ibilẹ Ile-Tuntun to wa laduugbo Mapo n’Ibadan pe ki ile-ẹjọ fopin si ibaṣepọ oun atọkunrin naa.
Ṣugbọn nṣe lọkunrin naa tun bẹrẹ sí i bẹbẹ, o ni ki igbimọ awọn adajọ ba oun bẹ obinrin naa ko ma kọ oju oun soorun alẹ.
Nigba to n rọ ile-ẹjọ lati fopin sí igbeyawo ọlọdun mẹrindinlogun (16) ọhun, Toyin sọ pé ẹṣin inu iwe lọkọ oun, ko le ṣọkọ fobinrin rara ati pe odidi ọdun mẹwaa lo kan fi n sun bọlọku sẹgbẹẹ oun lasan ti i ki i ṣe ojuṣe to yẹ ki ojulowo akọ ṣe lori abo.
Bakan naa lo ṣapejuwe ọkọ ẹ gẹgẹ bii alainilaari èèyàn, to jẹ pe oun loun gbọ bukaata rẹ ninu ile.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ọkọ mi kò le ṣe, nṣe ni mo lọọ loyun fún ọkunrin kan lati ita lati le gba a (ọkọ ẹ) silẹ lọwọ itiju ọrọ ti awọn eeyan n sọ pe ẹṣin inu iwe lasan ni.
Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, mo ti kuro ninu ile fun un, mo kuro ninu ile ti mo fowo ara mi kọ, mo n sun si ṣọọṣi bii ẹni ti ko nile lori.
“Oluwa mi, mi o le wa pẹlu ọkunrin yii mọ,mo fẹ kẹ ẹ fopin si igbeyawo yii ko ba tiẹ jade ninu ile mi.”
Ninu awijare tiẹ, Dọtun so pe loootọ loun ni ipenija ilera eyi ti ko jẹ ko ṣee ṣe foun lati fun obinrin loyun, eyi ni ko sì jẹ kí oun binu nigba tiyawo oun gbe oyun ale waa ka oun mọle.
O waa rọ ile-ẹjọ lati ma ṣe gba ẹbẹ iyawo oun wọle, kaka bẹẹ, nṣe ni ki wọn ba oun bẹ ẹ ko jẹ ki awọn jọ maa ba ere aniyan awọn tẹsiwaju.
Ṣugbọn ọrọ olupẹjọ ni wọn tẹle ni kootu pẹlu bi igbimọ awọn adajọ, labẹ akoso Oloye Henry Agbaje ṣe fopin sí igbeyawo ọlọdun mẹrindinlogun náà ,ti wọn si pa Dọtun laṣẹ lati jade kuro nile obinrin to ti di iyawo rẹ atijọ yii laarin ọjọ meje pere.