Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Yaqub Ganiyu nikan lo le ṣapejuwe iru ibanujẹ to wa lọkan ẹ latigba ti iyawo ẹ, Muridia, ti wọn ti jọ gbe fọdun mẹtadinlogun (17), sọ pe oun kọ lo ni akọbi ọmọ wọn, Zainab, ọmọ ọdun mẹrinla.
Ọmọ mẹrin ni ọkunrin ọlọkada yii atiyawo ẹ ti bi funra wọn, ṣugbọn eyi to jẹ akọbi ni ọrọ wa lori ẹ bayii, nitori ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Tẹslim, ti dide bayii pe oun ni baba ọmọ naa, oun si ṣetan lati gba a, bẹẹ ni iya rẹ naa si ni Tẹslim ni baba Zainab, Yaqub kọ.
Aipẹ yii ni aṣiri ọrọ yii ṣẹṣẹ tu si Yaqub lọwọ, ẹẹmeji ọtọọtọ lo si daku rangbọndan nigba tiyawo naa tu aṣiri yii fun un laarin oru.
Iwe iroyin oloyinbo, Vanguard, lọkunrin to n gbe ni Matomi, l’Agbado, naa ṣalaye ara ẹ fun, ohun to sọ fun wọn ni pe, nigba ti Muridia n kọṣẹ lọwọ loun pade ẹ, iyẹn lọdun mẹtadinlogun sẹyin. O loun ran an lọwọ lati kọṣẹ ọhun tan, oun si mu un kuro niluu wọn ti i ṣe Otu, nipinlẹ Ọyọ, oun mu un wa s’Ekoo lati jọ bẹrẹ igbesi aye lọkọ-laya papọ, ati lati da a lokoowo to le maa ṣe.
Ọmọ to kọkọ bi naa ni Zainab ti ẹlomi-in fẹẹ gba yii, ọkunrin mẹta lawọn yooku gẹgẹ bi Yakubu ṣe wi. Nnkan n dun latibẹrẹ bo ṣe wi, paapaa nigba ti iṣẹ awọn to n ṣe katapila toun yan laayo n lọ deede, towo n wọle daadaa.
“Nigba ti iṣẹ yẹn bọ mọ mi lọwọ, bi mo ṣe di ọlọkada niyẹn, ka ṣaa le maa rọna ati jẹun.
“Laipẹ yii ni mo ṣakiyesi pe iyawo mi n ṣe bakan si mi, mi o sọrọ, nitori mi o fẹ ki wahala ṣẹlẹ laarin wa. Afi nigba to mu foonu Tecno-5 kan wale, nigba ti mo beere pe nibo lo ti ri i, ko ri ọrọ gidi kan sọ. Mo fura pe o maa n ba ọkunrin kan ti mi o mọ sọrọ lori foonu yẹn, bi mo ṣe gba foonu ọhun lọwọ ẹ niyẹn.
“Ni nnkan bii oṣu kan sẹyin niyawo mi ji mi laarin oru, to sọ fun mi pe emi kọ ni mo ni Zainab, akọbi wa. O ni ọrẹkunrin oun tẹlẹ to ti n gbe ni Germany bayii loun bimọ naa fun un.
“ Kẹ ẹ si maa wo o o, emi atọkunrin to loun bi Zainab fun yii jọ n gbele kan naa nigba kan ni o, ko too di pe o lọ siluu oyinbo.
“Ẹẹmeji ni mo daku nigba to sọrọ yẹn fun mi, awọn araale lo ra mi pada. Ohun to n jọ mi loju ni pe ọkunrin to loun bi Zainab fun yii, a tan mọra wa, ọrẹ mi si tun ni nigba kan. Ọkan ninu awọn iyawo baba ọkunrin yẹn ni anti temi.
“Ki lo waa de to fẹẹ gba ọmọ temi bayii, wọn ni nnkan o lọ deede fun un ni Germany to wa, pe afi ko lọọ gba ọmọ to bi sita wale, wọn ni ti ko ba gba ọmọ naa, ilẹ okeere to wa yẹn ko ni i bọ si i fun un. Iyẹn lo ṣe fẹẹ waa da ile temi ru o.
“Mo tiẹ kọkọ ro pe Muridia ko mọ ohun to n sọ ni, emi ṣi n pe awọn famili ẹ pe ki wọn maa ba mi gbadura fun un ko le baa gbadun, mi o mọ pe o lero mi lọkan to fẹẹ ṣe.
“Afi bo ṣe lọọ sọrọ naa fawọn So-Safe l’Abule-Iroko, ti wọn waa mu mi, ti wọn ti mi mọle. Awọn So-Safe paṣẹ pe ki n lọọ ko gbogbo ẹru mi kuro ninu yara kan ta a n gbe. Wọn tun ni ki n da foonu ti mo gba lọwọ iyawo mi pada fun un, ki n dẹ maa fun un lẹgbẹrun marun-un naira lọsọọsẹ fun itọju awọn ọmọ.
“ Awọn ẹbi wa ti da sọrọ yii o, ṣugbọn awọn ẹbi iyawo mi wa lẹyin ẹ, wọn fara mọ ohun to n ṣe.
“Eyi to buru ni pe ẹni to fẹẹ gbọmọ lọwọ mi yii tun waa n halẹ mọ mi pe ki n jinna sọmọ naa, o loun lowo toun le fi fiya jẹ mi ti mi o ba ṣọra mi. Emi to jẹ ọkada mẹta ni mo ni tẹlẹ, ki n le rowo tọju ile mi naa ni mo ṣe ta wọn, to waa jẹ pe ẹyọ kan ṣoṣo lo ku lọwọ mi bayii, iyẹn naa dẹ ree, mo n sanwo ẹ diẹdiẹ ni.”
Bẹẹ ni ọkunrin ti idaamu ọkan ba yii ṣe sọrọ, to si n sọ pe kawọn eeyan dide sọrọ yii, ki wọn ma jẹ ki wọn fọwọ ọla gba oun loju.
Ṣugbọn alaye iyawo ẹ, Muridia, yatọ. Obinrin naa sọ fawọn akọroyin pe oun ti loyun ọsẹ mẹfa fun Tẹslim koun too pade Yaqub.
O loyun naa ni Yaqub saba le ti ko mọ, oun ko sọ fun un pe oyun ti wa ninu oun, nigba to jẹ Tẹslim to foun loyun ko gba a, niṣe lo ni koun lọọ ṣẹ ẹ. Ọmọ naa ni Zainab, akọbi oun yii.
Maridia sọ pe oun ati Tẹslim jọ wa labule lasiko toun wa ninu oyun yẹn ni, ṣugbọn Yakubu n wa lati Eko, awọn si n rira awọn daadaa.
“Aṣerunlọṣọọ ni mi, ṣugbọn emi ati Yakubu ko gbe igbe alaafia nigba ta a jọ n gbe, nitori ko niṣẹ kankan lọwọ. Gbogbo igbiyanju mi lati kọ ọ silẹ ko bọ si i, oyun lo fi n de mi mọlẹ.
“Emi ni mo n gbale ta a n gbe, ile kẹrin ti mo maa gba ree, ko si jẹ ki n dale gba, ki n maa da gbe.
“Lọjọ kan ni mo gba ipe kan latọdọ ọrẹ Tẹslim, niṣe niyẹn n beere pe bawo loyun ọjọsi, mi o tiẹ da a lohun. Inu ṣọọṣi ni mo wa lọjọ kan ti mọlẹbi Tẹslim kan mu foonu Techno-5 kan fun mi, nibẹ ni Tẹslim pe mi si, to ni oun wa ni Germany, ṣugbọn oun ko ti i riyawo gidi kan fẹ nibẹ, pe wọn si ni boun ko ba lọọ gba ọmọ oun to wa nita, nnkan ko le rọgbọ foun.
“Ẹnu ẹ la wa ti emi ati Yaqub fi ja ni ṣọọbu mi, to jẹ awọn to wa nitosi da si i, wọn dẹ fi to So-Safe leti, lawọn iyẹn fi mu un lọ.
“ Awọn ẹbi mi ti gbọ sọrọ yii, a dẹ ti n ṣeto ba a ṣe maa ṣayẹwo ẹjẹ (DNA) lati mọ Baba Zainab gan-an.”
Ṣa, ọrọ yii ko ti i yanju, ko si daju pe yoo yanju kankan, afi bi wọn ba ṣayẹwo ẹjẹ lati mọ Baba Zainab, iyẹn ninu Yaqub ọlọkada ati Tẹslim ara Germany.