Gbenga Amos, Abẹokuta
Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, James Ikenna ati ọrẹ ẹ kan to ṣi n sa kiri bayii ti lẹjẹ lọrun, Oluwatosin Adefisayọ, ọdọbinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan ni wọn foganna lọọ ka mọ ibi tiyẹn ti n sun jẹẹjẹ lọganjọ oru, wọn si fipa ba a laṣepọ, wọn tun yin in lọrun pa lẹyin ti wọn ṣe e tan.
Ilu Ogijo, to wa laarin Ṣagamu si Ikorodu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, ni iṣẹlẹ laabi yii ti waye.
Ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ si wa, o sọ pe ile kan naa ni ọmọbinrin ti wọn ṣika pa yii n gbe pẹlu James. Wọn lọmọbinrin naa ṣẹṣẹ kawe gboye ni Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa nipinlẹ Ọṣun tan ni. Ile naa lawọn obi rẹ n gbe pẹlu, bo tilẹ jẹ pe yara wọn ko papọ.
Wọn ni niṣe lafurasi ọdaran yii ati ekeji rẹ fo iganna wọle sinu yara ọmọbinrin ọhun loru tọwọ ti pa tẹsẹ ti pa, wọn si ki ọmọọlọmọ yii mọlẹ, awọn mejeeji fipa ba a laṣepọ, nigba ti wọn tun ṣe tan, wọn yin ọmọbinrin naa lọrun pa.
Awọn obi ọmọbinrin yii ati awọn alajọgbele ni wọn ṣakiyesi nigba tilẹ ọjọ keji mọ, pe o da bii pe akọlu ti waye si yara oloogbe naa, nigba ti wọn si wọle, to jẹ oku ọmọbinrin ọhun ni wọn ba, niṣe ni wọn figbe ta.
Eyi lo mu ki wọn ke sawọn fijilante agbegbe ọhun, nibi tawọn fijilante yii ti n wa gbogbo kọrọ ati kọlọfin boya wọn le ri ẹni to ṣiṣẹ laabi yii, bẹẹ ni wọn ri James loke aja ile naa, nibi to sa pamọ si, o n wa ọna lati bọ silẹ, ni wọn ba mu un, wọn si lọọ ke si awọn ọlọpaa.
Nigba ti DPO ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Ogijo, CSP Onatufeh Umoh, de ibi iṣẹlẹ naa pẹlu awọn ọmọọṣẹ rẹ, wọn ba James ati oku ọmọbinrin naa, wọn fi pampẹ ofin mu un lọ si teṣan wọn, wọn tun ke sawọn obi rẹ pẹlu.
Lasiko iwadii wọn, afurasi ọdaran naa jẹwọ pe loootọ lawọn huwa buruku naa, ṣugbọn ki i ṣe pe awọn ni in lọkan lati pa Oluwatosin, awọn fẹẹ ba a laṣepọ lasan tẹlẹ ni, amọ nigba tawọn ri i pe ọmọbinrin naa darukọ wọn, to si da wọn mọ, eyi lo mu kawọn pinnu lati pa a, ko ma le tu aṣiri awọn.
Bakan naa lawọn obi James sọ ni teṣan ọlọpaa pe awọn yọnda oku ati aaye ọmọ ọhun fun ijọba, ki wọn fi iya to ba yẹ jẹ ẹ, tori iwa ipanle rẹ ti su wọn, awọn ti sapa lori ẹ titi, igba ti ko gbọran rara lawọn kọ ọ lọmọ.
Ṣa, James ti wa ni ẹka to n ri si iwa ọdaran abẹle ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, fun iwadii to lọọrin lori ọrọ yii.
Bakan naa lawọn agbofinro ṣi n wa gbogbo ọna lati mu ekeji rẹ to sa lọ.