Ọlọpaa yii wọ gau, owo ẹyin lo gba lọwọ agunbanirọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko
Ọga ọlọpaa lọkunrin yii, ASP Joseph Eyitere to n ṣiṣẹ ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Meiran, nipinlẹ Eko. Ṣugbọn ọkunrin rọgbọdọ naa ti fori jona nidii iṣẹ ọlọpaa, o si ti bẹrẹ si i gboorun ara ẹ bayii lahaamọ ti wọn sọ ọ si.
CSP Olumuyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa apapọ nilẹ wa lo sọrọ yii di mimọ l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin yii, lori ikanni tuita (twitter) rẹ.
O lawọn ti ṣeleri lati maa taṣiiri awọn ọbayejẹ agbofinro ti wọn n huwa ta ko ilana ati ofin ileeṣẹ ọlọpaa, awọn yoo si maa foju wọn han faye.
Adejọbi ni abẹtẹlẹ ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, (N50,000) ni ọlọpaa yii gba lọwọ agunbanirọ ti wọn forukọ bo laṣiiri, o loun fẹẹ ran an lọwọ lori ọrọ kan. Adugbo Ile-Iwe, l’Ejigbo, nipinlẹ Eko niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin yii.
Gbogbo ọrọ ajọsọ ti afurasi ọdaran ati agunbanirọ naa fi n ṣọwọ si ara wọn lori foonu, ti ọlọpaa naa n dunaa-dura iye to maa gba, ati ẹri to ṣafihan bi agunbanirọ naa ṣe fowo ọhun ṣọwọ si i, lo ja ranyin lori atẹ ayelujara laipẹ yii. Eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe tọpinpin fidio naa, ajere ọrọ ọhun si ṣi mọ Eyitere lori, lagbofinro naa ba dero ahamọ.
Wọn lọkunrin naa ti jẹwọ pe loootọ loun gba owo kọbẹ naa, iwadii si ti n tẹ siwaju.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin, tun sọ pe awọn ti lọọ gba owo aitọ naa jade ninu akaunti agbofinro yii, awọn si ti da a pada fun agunbanirọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹrin yii.
Wọn ni igbẹjọ abẹle, ni ilana ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ṣi n ba lọ na, ti wọn ba pari eyi ni wọn maa taari Joseph siwaju adajọ lati lọọ gba sẹria to tọ si i.

Leave a Reply