Jamiu to gun oloṣo to ba lo pọ pa l’Abẹkuta ni: Ẹ ba mi bẹ ijọba ki wọn ma pa mi, mi o fẹẹ ku

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣe ẹ ranti Jamiu Malọmọ? ọmọ ọdun mejidinlogun tawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun mu laipẹ yii pe o gun aṣẹwo ti wọn jọ ba ara wọn sun l’Abẹokuta pa? Ọmọkunrin naa ti sọrọ, o loun ko deede gun oloṣo naa torukọ ẹ n jẹ Asisa Akande pa, oun lo foun loogun oloro mu kawọn too ṣere rara, ohun ti ko si jẹ koun mọ ohun toun n ṣe niyẹn toun fi gun un pa.

Ninu alaye ti ọmọ to ṣẹṣẹ ti ẹwọn de loṣu diẹ sẹyin naa ṣe fun ẹka iroyin ayelujara Platform times lo ti sọ pe oogun tijọba ti fofin de, iyẹn Tramadol, ni Asisa foun lati lo, koun le ko ibasun fun un daadaa yatọ si ṣereṣere.

Jamiu ni oun ko ṣẹṣẹ maa gbe ọmọbinrin yii jade tawọn yoo lọọ ba ara wọn ṣe aṣepọ, o ni yoo ti to igba mẹta tawọn ti n ṣe kinni fun ara wọn. O fi kun un pe ile awọn obi oun tawọn jọ n gbe loun gbe e lọ lalẹ ọjọ naa, l’Oke-Arẹgba, l’Abẹokuta, awọn si fi adehun si ẹgbẹrun mẹwaa naira, oun si gba lati fun un lowo naa lẹyin tawọn ba ṣere tan.

 Nigba ta a ṣere tan lalẹ ọjọ yẹn, mo ko ẹgbẹrun mẹjọ fun un dipo mẹwaa ta a jọ sọ, o loun ko ni i gba a ti ko ba pe, mo waa ni ko jẹ ka lọ sita, pe ma a fun un lẹgbẹrun meji to ku. Nigba ta a deta, mo mu foonu mi fun un, mo ni ko jẹ ki n lọọ mu ẹgbẹrun meji naa wa, ni mo ba wọle lọ.

“Nigba ti mo denu ile, mo mu ọbẹ kan jade, bi mo ṣe de ọdọ ẹ pada ni mo fi ọbẹ yẹn gun un lọrun, bo ṣe ṣubu lulẹ ni mo ko ẹgbẹrun mẹjọ ti mo ti fun un tẹlẹ, mo wọle pada ni temi.

“Ki i ṣe pe mo fẹẹ pa a, ẹẹkan pere naa ni mo fi ọbẹ yẹn gun un lọrun, mi o mọ pe o maa ku. Oun lo fun mi ni Tramadol pe ki n lo o ka too bara wa sun, o ni o maa jẹ ki n le ṣe daadaa ju oju lasan lọ. Oogun yẹn lo ti mi, nitori ẹ ni mi o ṣe mọ nnkan ti mo n ṣe, mi o mọgba ti mo gun Asisa lọbẹ. Nitori ẹ gan-an ni mi o ṣe sa lọ nigba ti mo gun un tan, mo jokoo sinu yara mi ni, mo n gbọ bawọn eeyan ṣe n sọrọ, ara mi o balẹ, ṣugbọn mi o sa lọ.

“Ẹ ba mi bẹ ijọba ki wọn ma pa mi, mi o fẹẹ ku. Ti wọn ba le dariji mi, mi o ni i ṣe bẹẹ mọ”

Bẹẹ ni Jamiu, ọmọ ọdun mejidinlogun to ni ọdun kẹta ree toun ti n gbe awọn oloṣo kiri sọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu keje, lawọn olugbe Ilupeju, Oke-Arẹgba, l’Abẹokuta, deede ba oku ọmọbinrin kan lori apata kan laduugbo naa, apa ẹjẹ wa lọrun rẹ nibi ti wọn ti gun un lọbẹ, bẹẹ si ni ọbẹ ti wọn fi gun un pa naa wa lẹgbẹẹ rẹ nibẹ.

Nigba ti alaga agbegbe naa, Adisa Lawal, lọọ fi to awọn ọlọpaa leti ni iwadii bẹrẹ, tọwọ fi ba Jamiu Malọmọ to jẹwọ pe oun loun pa ọmọbinrin naa, ati pe Asisa Akande lo n jẹ, oloṣo tawọn jọ ba ara wọn sun ni.

Leave a Reply