Jide Alabi
Amofin Eyitayọ Jẹgẹdẹ to dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ondo ti gbale ẹjọ lọ.
Lọjọ Eti, Furaidee, opin ọsẹ yii lọkunrin oloṣelu yii gbe ẹjọ ọhun lọ siwaju igbimọ to maa gbọ ẹjọ lori oriṣiiriṣii ẹsun to ṣu yọ nipa eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
Ninu eto idibo ọhun ni ajọ INEC ti kede pe Gomina Rotimi Akeredolu lo jawe olubori, ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ si ṣe ipo keji ninu idije naa.
Esi ibo yii ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii sọ pe ko tẹ oun lọrun, to si ti gbe Gomina Rotimi lọ siwaju igbimọ tiribuna, nibi ti wọn yoo ti tu ọrọ ọhun wo yẹbẹyebẹ.