Ẹni ti ẹgbẹ PDP fa kalẹ lati du ipo gomina ipinlẹ Ondo ninu ibo ti wọn yoo di nibẹ ni oṣu kẹwaa ọdun yii, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ko jẹ ki kinni naa tutu rara o. O ti fohun ranṣẹ si Gomina Rotimi Akeredolu ti yoo du ipo naa lorukọ ẹgbẹ APC pe ki Arakunrin naa tete maa ko ẹru rẹ kuro nile ijọba.
Ọrọ akọkọ ti Jẹgẹdẹ yoo ba awọn oniroyin sọ lẹyin to ti wọle nibi ibo abẹle ẹgbẹ wọn di lo ti ni bi PDP ṣe fa oun kalẹ yii, ibẹrẹ opin ijọba Akeredolu ni Ondo lo de yii. O ni oun ati awọn ara Ondo lawọn yoo jọ pawọ pọ le Arakunrin naa lọ.
Jẹgẹdẹ sọ bayii pe: “Pẹlu agbara Ọlọrun ati atilẹyin gbogbo awọn ara ipinlẹ Ondo pata, a oo gbajọba ipinlẹ yii kuro lọwọ Akeredolu ninu oṣu kẹwaa.” Bi eleyii yoo ṣee ṣe bi ko ni i ṣee ṣe, o digba naa na, ka too f’ọmọ Ọba f’Ọṣun.