‘Jibiti ni ofin ọdun 1999, afi ki wọn fagi le e’

Arọwa ti lọ setiigbọ awọn orilẹ-ede nla bii Amẹrika, Britain, France, Russia, Germany atawọn mi-in ti wọn tun jẹ ilu nla, pe ki wọn dẹkun ati maa ta nnkan ija fun Naijiria, nitori araalu ni awọn ijọba n fi nnkan ogun naa pa laye Dẹmokiresi to yẹ ko jẹ ijọba tiwa-n-tiwa.

Awọn agbaagba ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Yoruba ni Guusu Naijiria atawọn ti wọn n pe ni Middle Belt ni wọn n parọwa yii fawọn alagbara agbaye.

Yatọ si Ọjọgbọn Banji Akintoye to ṣoju ilẹ Yoruba lori arọwa yii, awọn mi-in ti wọn tun jọ kọwe sawọn orilẹ-ede agbaye yii ni Olori awọn Ohanaeze Ndigbo tẹlẹ, Oloye Nnia Nwodo, Ọjọgbọn  Yusuf Turaki, Amofin Tony Nnadi, Alaga ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Wale Adeniran atawọn mi-in.

Awijare awọn ẹgbẹ ajijagbara bii Ilana Ọmọ Yoruba, Lower Niger Congress ati Middle Belt Forum ni pe owo buruku tijọba wa n ya lọwọ awọn ilu okeere yii naa ni wọn fi n ra nnkan ija ogun, bẹẹ, awọn ibọn nla nla ti wọn fowo ọhun ra ko wulo fun araalu. Awọn Boko Haram, ISIS, Fulani darandaran, awọn ajinigbe atawọn oniṣẹ ibi yooku ni wọn n ko nnkan ija yii fun, tawọn yẹn si fi n pa araalu to ba ṣeeṣi beere ẹtọ rẹ pẹnrẹn.

Wọn ṣalaye bo ṣe jẹ pe Fulani n wọnu oko oloko pa wọn ni Naijiria, iyẹn lẹyin ti wọn ba jẹ oko ọhun run tan. Wọn sọ nipa bi wọn ṣe n gbe ibọn dani ti wọn yoo maa ba iyawo lo pọ loju ọkọ ẹ, wọn ṣalaye nipa bi wọn ṣe n da mọto lọna ti wọn yoo ji awọn eeyan wọgbo lọ raurau, to jẹ owo ribiribi lawọn ẹbi onitọhun yoo san ki wọn too da a silẹ, bi ko si wu wọn ki wọn da a silẹ, wọn yoo pa a ti kinni kan ko ni i ṣe ni.

Wọn ṣalaye fawọn ilu oyinbo yii pe beeyan ba beere ẹtọ ẹ ni Naijiria bayii, wọn yoo gbe tọhun janto ni, o di ẹyin gbaga.

Iwe ti wọn kọ ṣọwọ naa sọ ọ di mimọ pe ẹtọ tawọn akọroyin ni lati ṣiṣẹ wọn lai si ibẹru ko si nibẹ mọ bayii ni Naijiria, nitori ohun to wu ijọba ni wọn fẹẹ maa gbọ, ẹka iroyin to ba n ṣalaye ọrọ bo ṣe ri yoo jiya labẹ ofin ni. Koda, ẹka ayelujara paapaa ki i ṣe ibi kan teeyan ti le fi ero ọkan rẹ han bo ṣe fẹ ni Naijiria toni, ijọba lo n ṣakoso ohun ti yoo jade nibẹ, nibi to buru de niyẹn.

Fun awọn idi yii, awọn ẹgbẹ to n pe fun idaduro ẹkun kọọkan yii lawọn bẹ awọn orilẹ-ede to ti goke agba yii, pe ki wọn yee ya Naijiria lowo mọ, ki wọn si yee ta nnkan ija tijọba fi n doju ija kọ araalu fun wọn mọ, fun anfaani awọn alaiṣẹ to n jiya bii ẹran oriso lọwọ ijọba to wa lori aleefa ni Naijiria.

Lakootan ipẹ awọn eeyan yii, wọn ni awọn fẹ ki wọn fagi le ofin ilẹ Naijiria ta a n lo lọwọ, eyi ti wọn ṣe lọdun 1999. Wọn ṣalaye pe jibiti aye ni ofin naa, paapaa fawọn eeyan apa Guusu atawọn to wa ni Middle Belt, nitori awọn eeyan naa ko lọwọ ninu ofin yii nigba ti wọn n ṣe e, awọn apa Oke-Ọya to pe fun lo roko sọdọ ara wọn.

 

Leave a Reply