Jọkẹ Amọri
Oṣiṣẹ banki ilẹ wa kan, Adeyẹmi Tosin, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ti dero ahamọ ọlọpaa n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nigba tawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin mu un lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, fun ẹsun didari owo ọkan lara awọn kọsitọma ẹ, Ọgbẹni Adisa Quadri Ọladele, ẹni ọdun mejidinlọgọrin, sinu akaunti ara ẹ.
Ba a ṣe gbọ, banki UBA (United Bank for Africa) ni Tosin n ba ṣiṣẹ gẹgẹ bii kaṣia (cashier), iyẹn ọkan lara awọn to maa n gbowo wọle tabi sanwo fawọn kọsitọma lori kanta.
Wọn ni kọsitọma naa, Ọladele, lọ si ẹka banki UBA ọhun to wa n’Ibadan lọjọ kejila, oṣu kejila, oṣu kẹjọ yii, lati lọọ fi kaadi to fi n gbowo lẹnu ẹrọ, iyẹn kaadi ATM, gbowo, ṣugbọn niṣe ni kaadi naa ha sẹnu ẹrọ naa, lẹrọ ba gbe kaadi rẹ mi.
Eyi lo mu Quadri wọnu banki, o lọọ sọ iṣoro rẹ fun afurasi ọdaran naa pẹlu ireti pe yoo le ran oun lọwọ lati gba kaadi rẹ pada, ṣugbọn niṣe ni wọn ni ko lọ si ẹka banki to fun un ni kaadi lati lọọ gba kaadi mi-in ni.
O to ọjọ mẹrin lẹyin naa ko too ri kaadi tuntun gba, ẹyin ọjọ mẹrin ọhun ni Quadri too ri i pe wọn ti fa owo rẹpẹtẹ yọ ninu akaunti oun, miliọnu mẹwaa naira (N10 million) si ti poora ninu akanti rẹ, lo ba figbe ta, to si lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa ni teṣan wọn to wa lagbegbe Challegbe, n’Ibadan.
Nigba tawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii, ko pẹ rara taṣiiri fi tu pe owo to poora naa ti huyẹ, o si ti balẹ sinu akaunti Tosin, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.
Ni teṣan, wọn ni Tosin jẹwọ pe ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, loootọ loun ‘wọke’ owo olowo naa, o ni awọn koodu (code) aṣiri kan tawọn gbaju-ẹ fi n lu jibiti loun tẹ sori kaadi ATM kọsitọma yii to ha sẹnu ẹrọ lọjọsi, loun ba dari owo rẹ sinu akaunti oun.
Wọn lo tun jẹwọ pe oun palẹmọ lati rin irin-ajo lọ siluu oyinbo ni taṣiiri fi tu yii.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adewale Oṣifẹsọ, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan, o ni iwadii ṣi n tẹ siwaju, ati pe Tosin yoo balẹ sile-ẹjọ laipẹ.