Lọjọ to yẹ ki kootu gba beeli awọn ọmọ Igboho ladajọ gba oke okun lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ yii, ni gbogbo eto lati gba oniduuro awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho mejila to wa lahaamọ pe. Afi bi wọn ṣe dele-ẹjọ giga ijọba apapọ l’Abuja ti wọn ni Adajọ Obiora Egwuatu to yẹ ko buwọ luwe beeli naa ti kuro ni Naijiria,wọn lo ti rin irin-ajo lọ soke okun fun idanilẹkọọ.

Ko sẹni ti ara fu tẹlẹ pe eyi yoo ṣẹlẹ, koda, lọọya awọn ọmọ Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, sọ pe nigba toun de ọfiisi adajọ ni wọn too sọ foun pe ọkunrin naa ti tirafu. O ni wọn sọ pe pajawiri nibi to lọ naa, asiko perete ni wọn si fun un lati palẹmọ. Iyẹn lo fa a to fi gba oke okun lọ lai si eto kankan fawọn eeyan to ku diẹ ki wọn pe aadọta ọjọ lahaamọ.

Ṣe ohun ti kootu sọ fawọn olujẹjọ naa tẹlẹ ni pe ki wọn too le gba beeli wọn, ẹnikọọkan wọn gbọdọ ni oniduuro meji-meji.  Ọlajẹngbesi to jẹ agbẹjọro wọn sọ pe lọsẹ to kọja yii ni awọn oniduuro naa ti pe, wọn jẹ mẹrinlelogun.

O ni ṣugbọn kaka kile-ẹjọ tu awọn eeyan naa silẹ nigba ti wọn ti ṣe ohun ti kootu n fẹ, niṣe ni wọn tun ni awọn ni lati kọ lẹta si ọfiisi awọn oniduuro mẹrinlelogun naa, lati fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ṣetan lati duro fawọn ọmọ ẹyin Igboho mejila ti wọn wa latimọle.

Nigba ti ọrọ ri bayii, Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi rọ ile-ẹjọ lati gbe adajọ mi-in dide rọpọ Obiora Egwuatu ti wọn lo lọ fun idanilẹkọọ loke okun yii, ki wọn ma tun fi tiẹ da awọn ẹni ẹlẹni duro sahaamọ lẹyin ti wọn ti pẹ nibẹ bii eyi.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ yii, ni Adajọ Obiora ti kọkọ faaye beeli silẹ fawọn mejila naa, afi bo ṣe tun jẹ pe inu akolo DSS naa ni wọn ṣi wa lẹyin ọjọ gbọọrọ.

Awọn ọmọ ẹyin Igboho ti wọn wa lahaamọ lati ọjọ kin-in-in, oṣu keje, ọdun 2021, tawọn DSS ti lọọ da wahala silẹ nile ajijagbara naa ni: Abdulateef Ọnaọlapọ, Tajudeen Irinloye, Diẹkọla Ademọla,Ayọbami Donald, Uthman Adelabu, Ọlakunle Oluwapẹlumi,Raji Kazeem, Taiwo Tajudeen, Amudat Babatunde, Abideen Shitu, Jamiu Oyetunji ati Bamidele Sunday.

Nnkan bii aago kan oru ọjọ naa ni awọn DSS ya bo ile Igboho, n’Ibadan, ti wahala nla bẹ silẹ nile ajijagbara naa laarin oru. Koda, Agbẹnusọ awọn DSS, Peter Afunanya, fidi ẹ mulẹ pe awọn pa meji ninu awọn ọmọ ẹyin Igboho lasiko tawọn jọ kọju ija sira awọn.

Ohun ti wọn tori ẹ dele Igboho loru ni pe wọn ni o ni nnkan ija ogun nile, bẹẹ ni iwa ọdaran to lodi sofin ilu kun ọwọ rẹ atawọn to n ba a tọju nnkan ogun to kọ jọ sile rẹ ni Soka, n’Ibadan. Lọjọ naa lawọn eeyan yii ti wa lakolo ijọba.

Leave a Reply