Kareem fipa ba ọmọ bibi inu ẹ lo pọ, ọlọkada naa ṣe ‘kinni’fọmọ iya alagbo n’Ibadan

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Tunde Kareem, ti dero atimọle ajọ aabo ara ẹni laabo ilu, iyẹn, Nigeria Security and Civil Defense Corpse (NSCDC), l’Agodi, n’Ibadan bayii, wọn lo fipa ba ọmọ bibi inu ẹ laṣepọ.

Pe Kareem lo bi ọmọdebinrin ti wọn lo fipa ba laṣepọ yii nikan kọ lọran to da, ọran nla keji to wa nibẹ ni pe ọmọ ọhun ko ti i ju ọmọ ọdun mọkanla pere lọ.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, lọwọ ajọ NSCDC tẹ ọkunrin ọmọ bibi ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, to fi adugbo Papa, Idi-Ọsan, lagbegbe Olodo, n’Ibadan, ṣebugbe yii, lẹyin ti wọn rẹni ta wọn lolobo nipa iṣẹlẹ kayeefi naa.

Ṣugbọn baba naa sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ, o ni iya ọmọ naa to jẹ iyawo oun atijọ lo mọ-ọn-mọ purọ ẹsun naa mọ oun lati kan fi ba oun lorukọ jẹ nitori pe oun ti fẹ iyawo mi-in lẹyin ti oun ti kọ ọ silẹ.

Bakan naa lọwọ awọn Sifu Difẹnsi tẹ ọkunrin ọlọkada kan, Amos Michael to wọn lo fi agbalagba ara ba ọmọ ọdun mẹwaa, ọmọ ọlọmọ ti ko ti i mọ nnkan kan laṣepọ.

Wọn ni baba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta yii fi kinni nla ẹ fa ọmọọdun mẹwaa naa labẹ ya, ṣugbọn baba naa sọ pe oun ko ti ‘kinni’ oun bọ ọ labẹ, ika ọwọ oun lasan loun fi ro o loju ara.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, ni Alukoro ajọ ẹṣọ alaabo ilu nipinlẹ Ọyọ, Oyindamọla Okunẹyẹ, ṣafihan awọn afurasi ọdaran mejeeji yii lolu ileeṣẹ wọn to wa l’Agodi, n’Ibadan.

Alukoro wọn fidi ẹ mulẹ pe agbo niya ọmọ ti Amos fipa ba laṣepọ n ta, Amos si jẹ ọkan ninu awọn ọlọkada to maa n lọọ mu agbo jẹdi ati ọpa ẹyin nibẹ.

Okunẹyẹ fidi ẹ mulẹ pe “anfaani ajọṣepọ to wa laarin awọn ọlọkada yii pẹlu iya alagbo yẹn ni Amos lo to fi sun mọ ọmọbinrin ọhun.

“Lọjọ to maa ṣiṣẹ ibi yẹn, niṣe lo fi ọkada rẹ gbe ọmọ yẹn lọ si kọrọ ibi kan, to si fipa ba a laṣepọ.

Ninu awijare ẹ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Amos, ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi, ṣugbọn to fi adugbo Alakia, n’Ibadan, ṣebugbe, sọ pe oun ko ba ọmọ naa laṣepọ.

“Nibi ta a ti maa n mu agbo ni mo ti mọ ọmọ yẹn. Lọjọ yẹn, loootọ ni mo fi ọkada gbe e lọ sibi ti mo ti ba a ṣere, ṣugbọn mi o ba a laṣepọ, mo kan ti ika bọ ọ labẹ lasan ni”.

Amọ ṣaa, ọga ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adaralẹwa Michael, ti ṣeleri lati gbe awọn afurasi ọdaran mejeeji naa lọ sile-ẹjọ ni kete ti awọn ba pari iwadii lori awọn iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply