Adewale Adeoye
Eeyan marun-un ti wọn jẹ mọlẹbi kan naa, ti wọn n gbe ni agboole ajọgbe kan ti wọn n pe ni ‘Shagari Quarters’ to wa lagbegbe Dei-Dei, niluu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa, lawọn agbebọn kan ti ji gbe nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe gbara tawọn oniṣẹ ibi naa raaye wọ’nu ọgba agboole naa ni wọn lọ taara sinu yara ọga agba kọsitọọmu kan, ti wọn si ji iyawo rẹ, ọmọ rẹ mẹta ati aburo rẹ kan ti wọn ba nile lọjọ naa lọ.
O le ni wakati meji daadaa ti wọn lo layiika naa ti ko sẹnikankan to le gbena woju wọn rara nitori ibọn gidi lo wa lọwọ wọn. Lẹyin ti wọn tẹ ara wọn lọrun tan ni wọn ba tun dori kọ agbegbe kan ti wọn n pe ni Dakwa.
Ilu Abuja ni ọga kọsitọọmu ọhun to si maa n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa ‘Rapid Response Squad’ (RRS), ṣugbọn laipẹ yii niṣẹ gbe e lọ siluu Eko. Eyi lo mu ko fi awọn ẹbi rẹ siluu Abuja, nibi to n gbe tẹlẹ. Ile naa ni wọn wa tawọn agbebọn fi lọọ kogun ja wọn lojiji bayii.
Nigba to maa fi di ọjọ keji, awọn agbebọn ju iyawo kọsitọọmu naa silẹ, nitori to wa nipo iloyun. Ṣugbọn ọdọ wọn lawọn yooku wa bayii, ti ko sẹnikankan to mọ ibi ti wọn ko wọn pamọ si, ti wọn ko si ti i pe mọlẹbi wọn lati sọ pe ohun bayii lawọn fẹẹ gba lọwọ wọn ko too di pe wọn maa ju wọn silẹ lahaamọ ti wọn wa.
Olori ilu Dakwa, Oloye Dọkita Alhassan Musa Babachukuri, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, sọ pe awọn agbebọn ọhun gbiyanju lati wọnu ilu awọn, ṣugbọn awọn ọdẹ tawọn gba sẹnu geeti ko gba fun wọn rara, bi wọn ṣe n yinbọn fawọn ọdẹ naa ni awọn naa n da a pada fun wọn. Nigba tawọn oniṣẹ ibi naa ri i pe awọn ọdẹ naa ko mu ọrọ ọhun ni kekere ni wọn ba sa lọ.
Musa waa rawọ ẹbẹ sawọn alaṣẹ ijọba ilu Abuja pe ki wọn gbiyanju lati kapa awọn oniṣẹ ibi ti wọn ti fẹẹ sọra wọn di nnkan babara laarin ilu. O ni ẹyin apata nla kan ti wọn n pe ni ‘Zuma Rock’, to wa lagbegbe Chachi, nipinlẹ Niger, ni ọpọ awọn oniṣẹ ibi naa maa n sapamọ si lẹyin ti wọn ba ti ṣiṣẹ ibi ọwọ wọn tan.