Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Afi bii fiimu agbelewo ni iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ ninu ọgba ile-ẹjọ to wa lagbegbe Ọka, niluu Ondo ṣi n jẹ fawọn eeyan to wa nibẹ, iyẹn nigba ti baba agbalagba ẹni aadọrin ọdun kan to waa ṣẹlẹri nile-ẹjọ ṣe deedee ṣubu lulẹ, to si ṣe bẹẹ ku sinu kootu laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ki i ṣe baba ta a n wi yii lo waa jẹjọ ni kootu, ẹri lasan ni wọn loun ati ọrẹ rẹ kan ti wọn jọ wa lọjọ naa waa jẹ ninu igbẹjọ kan to n lọ lọwọ.
Ibi tawọn eeyan ti jokoo laaarọ ọjọ naa, ti wọn si n fi suuru duro de adajọ to n gbọ ẹjọ ni wọn ni baba ti ko ṣẹni to mọ orukọ rẹ naa ti yi ṣubu lojiji lori aga to jokoo si, to ba la ori mọ ilẹẹlẹ ti wọn fi taisi to wa nile-ẹjọ ọhun.
Kiakia lawọn eeyan to wa ninu kootu lasiko naa ti sare ṣugbaa rẹ, ti wọn si gbiyanju ati gbe e dide, ki wọn too ṣakiyesi pe o ti ku patapata.
Ọgbẹni Tunde Ariyọ ni awọn oṣiṣẹ kootu kan ni wọn sare pe awọn ọlọpaa lati teṣan Ẹnu-Ọwá, ti wọn si tun ṣeto ọkọ anbulansi ti wọn fi gbe oku baba naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa niluu Ondo.
Niṣe ni gbogbo awọn to wa ni agbegbe ile ẹjọ naa n fọwọ luwọ, ti aọn mi-in si n wo tiyanu tiyanu pe iru iṣẹlẹ wo niyi. Wọn ni baba to jade nile rẹ ti ohunkohun ko ṣe to fi fẹẹ wa ṣẹlẹrii ni kootu, to waa deede ṣubu lulẹ, to si gbabẹ lọ sọrun jẹ kayeefi patapata.
Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe o da bii pe ọrọ naa ki i ṣe oju lasan, abi bawo ni eeyan ṣẹ n deede ku bẹ ẹ. Wọn ni ko ma jẹ pe ẹni o ni ẹjọ ti wọn fẹẹ waa ṣẹlẹri fun lo ti tawọ si wọn. Ṣugbọn eyi to wu ko jẹ, ohun ti ALAROYE le fidi rẹ mulẹ ni pe lasiko ti baba agbalagba naa fẹẹ waa ṣẹlẹrii ni kootu ti wọn si n duro de adajọ lo ṣubu lulẹ, lo ba ku si kootu.