Iyalẹnu lo ṣi n jẹ fun gbogbo eeyan nigba ti wọn gbọ pe oku wọle ibo l’Amẹrika. Niṣe lawọn eeyan dibo fun un rẹpẹtẹ, to si wọle gẹgẹ bii ọmọ ileegbimọ aṣofin ilu kan ti wọn n pe ni Dakota.
David Andahl lorukọ ọkunrin ẹni ọdun marunlelaaadọta naa to jẹ ẹlẹran ọsin. O si wa ninu awọn ti wọn fa kalẹ ni agbegbe North Dakota, lati ṣoju awọn eeyan agbegbe naa. Ṣugbọn arun korona to kọ lu gbogbo aye pa ọkunrin naa ninu oṣu kẹwaa, to kọja yii.
Niwọn igba to si jẹ pe eto idibo Amẹrika to waye ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ti sun mọle, ti wọn ti forukọ rẹ sara apoti ibo, ko si bi wọn ṣe fẹẹ yọ orukọ rẹ kuro mọ.
Ko jọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu rẹ gan-an fọkan si i pe ẹnikẹni le dibo fun un niwọn igba to jẹ pe ki i ṣe nnkan aṣiri pe ọkunrin to maa n ṣiṣẹ ẹran naa ti ku.
Afi bo ṣe di ọjọ Iṣẹgun ti ibo waye l’Amẹrika, ti awọn eeyan ilu naa bẹrẹ si i dibo fun oku ọrun yii. O si ri ibo lọdọ awọn eeyan debii pe oun lo wọle ibo ni agbegbe to ti wa naa. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Aarẹ Donald Trump, Republican, ni.
Ọkunrin yii ni iba ṣoju awọn eeyan re pẹlu bi wọn ṣe dibo fun un yii, ṣugbọn korona to da ẹmi rẹ legbodo ko jẹ.