Kayeefi! odo kan naa ni maaluu atawọn eeyan Elebuẹ ti n mumi ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ohun iyalẹnu lo jẹ fun akọroyin ALAROYE, nigba to de ilu kan ti wọn n pe ni Elebuẹ, lagbegbe Alapata, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, nibi ti awọn araalu ati maaluu ti jọ n mu omi ṣẹlẹru, latari pe wọn ko ni omi rara niluu ọhun.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ilu naa ti wa lati ọdun pipẹ, ṣugbọn o nira fun wọn lati ri omi to ja gaara to mu, bu wẹ tori pe omi ṣẹlẹru ẹyọ kan ti wọn ni lagbegbe naa, eniyan ati maaluu ni wọn jọ n pin in mu.

Ọmọ Magaji iluu naa to ba oniroyin sọrọ, Abubakar Rasak, sọ pe oun ti le ni ogoji ọdun, ṣugbọn lati pinnisin ti oun ti gbọnju, omi ẹyọ kan ti awọn n pọn mu niyẹn, ibẹ naa lawọn maaluu naa si ti n mu, awọn jọ maa n pin omi naa mu ni. O tẹsiwaju pe idaji kutukutu ni awọn obinrin yoo ti ji lọ si odo naa lati lọọ pọn omi, ti wọn ba pẹ ti maaluu ba kọkọ debẹ, a jẹ pe ko si omi pipọn lọjọ naa niyẹn.

Ninu ọrọ rẹ, o jẹ ko di mimọ pe ibi omi ọhun tun jinna si ilu, maili meji ni odo naa wa si ilu, to si jẹ pe awọn obinrin ki i lọ sodo ju ẹẹkan lọ lojumọ, ti wọn ba lọ ni idaji oni, o tun di idaji ọjọ keji. Ọgbẹni Rasak ni ija ti kọkọ waye laaarin awọn Fulani darandaran ati araalu lori pe ki wọn maa jẹ ki maaluu wọ inu omi ọhun mọ, sugbọn ko si ayipada bii alara.

Awọn olugbe ilu naa ti waa rọ ijọba Kwara lati ran ilu wọn lọwọ nipa gbigbẹ omi to ṣee bu mu, bu wẹ, ki wọn le fopin si bi awọn eeyan ati maaluu ṣe n dijọ mu omi ṣẹlẹru.

Leave a Reply