Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn ọlọpaa ilu Mississippi, lorilẹ-ede Amẹrika ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori fidio oniṣẹju diẹ (Video Clips) kan to wa nita bayii, nibi ti Omidan Denise Fraizer, ẹni ọdun mọkandinlogun (19) kan ti n ba aja rẹ sun.
Awọn ọlọpaa naa sọ pe bawọn ba pari gbogbo iwadii awọn tan, ti Omidan Denise Fraizer si jẹbi awọn ẹsun naa, o ṣee ṣe ko lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa tabi ju bẹẹ lọọ.
ALAROYE gbọ pe ọkan lara awọn araadugbo ibi ti Fraizer n gbe ti wọn ri fidio naa ni wọn lọọ fẹjọ rẹ sun awọn ọlọpaa agbegbe naa, tawọn yẹn si waa fọwọ ofin mu un lọ sagọọ wọn.
Ninu ọrọ ọga ọlọpaa teṣan ti wọn ti waa mu Omidan Denise Fraizer, Ọgbẹni JD Carter to sọrọ nipa iwa radarada ti ọmọbinrin naa hu lo ti sọ pe lati nnkan bii ọdun mẹtadinlogun (17) sẹyin toun ti wa lẹnu iṣẹ ọlọpaa ọhun, oun ko gbọ iru ẹjọ bẹẹ ri, pe eeyan n ba aja rẹ sun. O ni ti omidan yii ni akọkọ iru rẹ toun maa gbọ.
O ni koda oniruuru aworan Fraizer ti ko boju mu rara lati gbe sita lo wa lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa naa bayii tawọn n ṣiṣẹ le lori.
Ṣugbọn ọmọbinrin naa ti sọrọ o, o ni ki i ṣe ifẹ inu oun rara lati ba aja naa sun gẹgẹ bi fidio ọhun ti ṣe wa nita bayii. O ni awọn kan ni wọn kan an nipa foun, ti wọn si tun n halẹ mọ oun pe ki oun gba lati jẹ ki aja naa laṣepọ pẹlu oun. O ni owo nla ni wọn gbe kalẹ pe awọn yoo fun oun toun ba ṣe bẹẹ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe ọmọbinrin yii ko ri ẹri kankan to fidi ọrọ ọhun mulẹ pe loootọ ni wọn fipa mu un, tabi pe wọn n halẹ mọ ọn lati ṣe bẹẹ.
Carter ni ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ naa ti n ṣiṣẹ lori ẹsun naa, o ni ijiya to tọ lawon maa fi jẹ Omidan Denise Fraizer bo ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an yii.
O ni ofin ilẹ naa ko faaye gba ẹnikẹni lati maa ba aja sun, tabi lati maa hu iwa radarada pẹlu ohun ọsin ninu ilu naa.
Bakan naa ni wọn ti gba aja naa kuro lọwọ ọmọbinrin yii, ti wọn si ti gbe e lọ sibi ti wọn ti n ṣetọju aja nilẹ naa fun itọju to peye.
Bakan naa ni wọn tun ti lọọ fi Fraizer naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi pari ẹjọ ti wọn n ba a ṣe lori rẹ.