Faith Adebọla
Pẹlu ikanra lawọn eeyan fi n ṣepe fun abilekọ ẹni ọdun mejilelogun kan, Khadija Yakubu, latari bi wọn ṣe lo fi majele sinu ounjẹ awọn ọmọ iyaale rẹ mẹrin, majele naa si ṣeku pa mẹta ninu awọn ọmọ naa, ikẹrin ṣi wa ni ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu to ti n gba itọju lọwọ.
Iwadii tawọn ọlọpaa ṣe gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade wọn ti wọn fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ni pe iṣẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti, Furaidee, nigba tawọn ọmọ naa mu tii gbigbona tobinrin yii po fun wọn tan laaarọ ọjọ ọhun nile wọn to wa lagbegbe Makara-Huta, nijọba ibilẹ Potiskum, nipinlẹ Yobe.
Awọn ọmọ mẹrin tiyaale naa bi fun ọkọ wọn, Yakubu Alhaji Haruna, ni Zainab Alhaji Haruna, ọmọọdun meje, Ahmed Alhaji Haruna, ọmọọdun mẹsan-an, Maryam Alhaji Haruna, ọmọọdun mọkanla ati Umar Alhaji Haruna, ọmọọdun mejila.
Wọn lafurasi ọdaran naa lo po tii (tea) fawọn ọmọ naa, ko si pẹ ti wọn mu tii ọran yii tan ni wọn bẹrẹ si i lọ inu mọlẹ, lawọn aladuugbo ba sare gbe wọn digbadigba lọọ sileewosan ijọba to wa nitosi.
Gbogbo itọju tawọn dokita fun wọn lo ja si pabo, mẹta ninu awọn ọmọ naa fo ṣanlẹ, wọn ku, ẹyọ kan ni wọn ṣi n du ẹmi ẹ lọwọ.
Wọn layẹwo tawọn dokita ṣe fihan pe majele ti wa ninu tii tawọn ọmọ naa mu ni.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe, ASP Dungus AbdulKarim, sọ ninu atẹjade rẹ pe awọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe Abilekọ Khadija, o ti wa lahaamọ awọn ọtẹlemuyẹ ti wọn n tọpinpin iṣẹlẹ ọhun.
O lawọn maa taari afurasi ọdaran naa sile-ẹjọ tiwadii ba ti pari.