Jide Alabi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, ti sọ fun awọn kọmiṣanna rẹ pe inu oun yoo dun ti eyikeyii to ba ni in lọkan lati dije dupo gomina lọdun 2022 tete kọwe fipo silẹ, ki wọn ma fi tiwọn ko ba iṣẹ idagbasoke toun ni lọkan.
Nibi eto pataki kan ti gomina yii gbe kalẹ lori ṣiṣe iṣẹ ilu bo ti yẹ ati amulo awọn eeyan to tọ fun iṣakoso ipinlẹ Ekiti lo sọrọ ọhun niluu Ado Ekiti, l’Ọjọbọ, Tọsidee.
Fayẹmi sọ pe oun gbe eto ọhun kalẹ lati fi ṣe odiwọn iṣẹ ti oun ti ṣe ni saa keji yii, ati ibi to ku si pẹlu erongba lati ṣatunṣe to dara fun ilọsiwaju ipinlẹ Ekiti.
Gomina Ekiti ti waa rọ awọn kọmiṣanna ẹ ti wọn ni in lọkan lati dije dupo gomina lọdun 2022, ki wọn tete kọwe fipo wọn silẹ, ki wọn ma baa fi ero tiwọn yii di iṣẹ idagbasoke ti oun ni lọkan fun awọn eeyan Ekiti lọwọ.
O ni, “Gbogbo awọn ti yoo ṣakoba fun ọkọ itẹsiwaju ti a ni lọkan fun awọn eeyan wa l’Ekiti, paapaa awọn to wa ninu ijọba mi, ni mo fẹ ki wọn fiṣẹ silẹ bayii, a ko ni i fẹ ohun to maa mu wa yapa kuro ninu ohun rere ta a fẹẹ ṣe.
“Lati le ṣaṣeyọri lo mu wa pe oloṣelu nla meji ti wọn ti jẹ gomina tẹlẹ ri, lati waa gba wa nimọran lori bi wọn ti ṣaṣeyọri ninu eto iṣakoso nigba ti wọn wa nile ijọba.
“Ohun ti a n ṣapero le lori ni awọn aṣeyọri wa lati bii ọdun meji sẹyin, nibi to ku si atawọn ọna abayọ mi-in lori bi Ekiti ṣe le dara ju bayii lọ.
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Babatunde Raji Faṣhọla, ati Senetọ Kashim Shettima, gomina ipinlẹ Borno, tẹlẹ ni wọn wa l’Ekiti fun ipade pataki ọhun.