Wọn ti mu ọlọpaa to gbowo lọwọ awakọ to rufin oju popo l’Ekoo

Jide Alabi

Ọlọpaa kan ti wọ wahala bayii lori bo ṣe gba owo lọwọ obinrin kan nitori tiyẹn gba ojuna ti ko yẹ l’Ekoo, bẹẹ ni ẹṣọ to n mojuto irinna, iyẹn LASTMA, ti da owo ti ọlọpaa yii gba pada fẹni to ni in.

Laipẹ yii ni Ọga agba fun ajọ LASTMA,  Ọgbẹni Ọlajide Oduyọye, kede iṣẹlẹ yii lori ikanni abẹyẹfo ẹ pe wọn fọrọ kan to oun leti pe ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ pẹlu LASTMA gba owo rẹpẹtẹ lọwọ awakọ kan lori ẹsun pe ọ gba ọna ti ko yẹ.

Ẹgbẹrun mejilelaaadọta (N52,000) naira ni wọn sọ pe ọlọpaa yii gba lọwọ obinrin to n wa mọtọ yii, ati pe ẹrọ apọwo (POS), lo fi gba a lọwọ ẹ.

Oduyọye sọ pe ọwọ ti tẹ ọkunrin ọlọpaa naa, ati pe LASTMA ti pe obinrin ti wọn fipa gba owo lọwọ ẹ, awọn si ti da owo ẹ pada fun un.

O ni, “Ẹsun to fi kan obinrin to gbowo lọwọ ẹ yii ni pe o wa mọto lojuna ti ko yẹ ko gba, loju ẹsẹ naa ni wọn ti wa ọkọ ẹ wa si olu ileeṣẹ wa. Nibẹ naa ni wọn ti bẹrẹ idunaa-dura, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150,000) gan-an lo ni ko lọọ mu wa, nigba ti wọn si jọ dunnaa-dura daadaa ni iyẹn gba lati fun un ni ẹgbẹrun mejilelaaadọta naira (N52,000). Maṣinni apọwo, iyẹn POS, lo fi gba owo ọhun sapo ara ẹ. Bi ọlọpaa yii ṣe gba owo ọhun tan ni obinrin ti wọn gbowo lọwọ ẹ yii ti pe nọmba ifisun LASTMA.

“Nibẹ naa lo ti ṣalaye pe ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ pẹlu LASTMA yan oun jẹ, o gba owo lọwọ oun.”

Oduyọye sọ pe nibi ti oun ti tara bọ ọrọ ọhun niyẹn o, ti ọwọ si pada tẹ ọlọpaa to huwa idọti ọhun, ti ajọ LASTMA paapaa si ti da owo obinrin naa pada fun un lọjọ ti oun ati iya ẹ waa ba awọn lọfiisi awọn.

Oduyọye ti sọ pe LASTMA ko ni i gba irufẹ iwa bẹẹ laaye, ati pe ohun to jẹ ajọ naa logun ni bi eto irinna ọkọ l’Ekoo yoo ṣe maa lọ geere, ti awọn awakọ paapaa yoo maa tẹle ofin irinna lai si wahala kankan.

Bakan naa lo sọ pe  LASTMA yoo fa ọkunrin agbofinro to huwa ọdaran yii le awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ki wọn le fi jofin gẹgẹ bo ti yẹ.

 

Leave a Reply