Ki laa ti waa ṣeyi si, wọn tun ji agbẹ kan gbe ninu oko ẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu ibẹru-bojo ikọlu awọn ajinigbe lawọn agbẹ agbegbe Moniya, niluu Ibadan, wa bayii, pẹlu bi awọn amookunṣika ẹda ṣe ji ọkan pataki ninu wọn, Ogbẹni Oluwọle Agboọla, gbe.

Awọn ajinigbe ọhun ti wọn jẹ mẹfa ni wọn mura bii ọmoogun orileede yii, ti wọn si ya wọnu oko baba naa to wa lọna Abule Nagbede, lagbegbe Mọniya, n’Ibadan lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe ẹsẹ lawọn olubi eeyan yii fi rin wọ inu ọgba ti wọn ti n sin ẹlẹdẹ atawọn ohun abiyẹ wọnyi. Eyi ni ko jẹ ki awọn oṣiṣẹ inu oko nla ọhun gburoo awọn alejo ọran naa titi ti wọn fi kan wọn lara. Aṣọ ṣọja ti wọn si wọ paapaa ba wọn lẹru to bẹẹ ti wọn ko mọ eyi ti wọn le ṣe titi ti awọn ọdaran fi naa ṣiṣẹ ibi ti wọn waa ṣe

Awọn ajinigbe ti wọn mura bii ṣọja wọnyi ko ṣe meni ṣe meji, ọdọ Ọgbẹni Agboọla ti i ṣe ọga agba oko nla naa ni wọn lọ taara, ti wọn si mu un wọnu igbo lọ.

 

Akitiyan awọn oṣiṣẹ inu oko naa lo jẹ ki wọn mọ pe ki i ṣe awọn ṣọja lo mu ọga wọn lọ bi ko ṣe awọn ajinigbe.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti lagọọ ọlọpaa to wa ni Mọniya lawọn ọlọpaa ti fọn da sinu gbogbo igbo to yi Mọniya ka lati wa awọn gbọmọgbọmọ ọhun kan, ki wọn si gba baba ti wọn ji gbe silẹ lọwọ wọn.

“Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn ikọ eleto aabo mi-in bii Amọtẹkun, Operation Burst atawọn ọdẹ ibilẹ naa ti darapọ mọ awọn ọlọpaa ninu igbo lati ri i pe wọn ṣaṣeyọri lori iṣẹ yii.” Bẹẹ ni SP Fadeyi lo sọ eyi fawọn oniroyin n’Ibadan.

Leave a Reply