Faith Adebọla
“Inira gidi maa wa ni Naijiria lọdun 2022. Ọwọngogo ounjẹ maa gogo si i. Ọrọ-aje ilẹ wa maa tubọ buru si i, koda, o maa takiti ni. Gbajugbaja oloṣelu kan maa fo ṣanlẹ lọdun 2022 yii, o maa dagbere faye. Ẹni to si maa bọ sipo aarẹ ilẹ wa maa ya awọn eeyan lẹnu gidi.”
Ẹnu gbajugbaja ajihinrere to tun jẹ olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church nni, Primate Elijah Babatunde Ayọdele, lawọn ọrọ to n bọ silẹ gbi gbi bii yinyin yii ti jade lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Lasiko to n sọrọ ninu ṣọọṣi INRI rẹ to wa l’Ekoo, Wolii Elijah sọ pe apara lọrọ tawọn oloṣelu kan n sọ pe awọn maa ṣeto agbegbe ibi ti aarẹ ti maa jade wa ni makan-makan loye n kan, o ni ọrọ roteeti ko le ṣiṣẹ, ati pe agbegbe Oke-Ọya tun ni aarẹ ti maa wa lẹyin Buhari.
“Ẹ gbagbe nipa roteṣan ipo aarẹ, mo ti sọ tẹlẹ pe agbegbe Ariwa ni aarẹ ti maa jade lẹyin ti Buhari ba ṣetan, tawọn eeyan Guusu o ba siriọsi. Awọn ipinlẹ kan maa dẹnu kọlẹ. Wọn maa gbaṣẹ lọwọ awọn minisita Buhari kan, wọn si maa sọ wọn dẹni yẹyẹ.
Ẹ sọ fun Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ pe ko ma ṣe ba igbakeji ẹ ja, aijẹ bẹẹ, aṣeni maa ṣe’ra ẹ ni, o si le ma rẹni foju jọ lagbo oṣelu mọ.
L’Ọṣun, afi ki ẹgbẹ oṣelu APC tete yanju lọgbọlọgbọ to n ṣẹlẹ laarin wọn, mi o ti i ri ọmọ oye ẹgbẹ PDP kan to maa fẹyin Oyetọla janlẹ fun saa ẹlẹẹkeji to fẹẹ lọ yii. Ṣugbọn oun naa gbọdọ san ṣokoto ẹ daadaa, tori wọn maa fẹ lati fọ ẹgbẹ oṣelu rẹ si wẹwẹ.
Laarin oṣu meji, ti Kayọde Fayẹmi ko ba wa nnkan ṣe si ija aarin ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ rẹ, o maa padanu ipo gomina sọwọ ẹgbẹ PDP lasiko ibo to n bọ. Gbogbo awọn to n bara wọn ja ninu ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ekiti gbọdọ fi igbanu kan ṣoṣo ṣ’ọja laarin ọjọ marundinlaaadọrin sasiko yii, bi wọn ba fẹ ki ẹgbẹ wọn wọle l’Ekiti.
Lori ọrọ ipo aarẹ, ki Tinubu gbaju mọ ọrọ oṣelu ipinlẹ Eko ni o, ko jawọ ninu didu ipo aarẹ apapọ. Awọn oloṣelu tuntun maa jade ti wọn ma gbajọba Naijiria.
Ẹkọ ko ni i ṣoju mimu fun Abubakar Malami o, o maa koju ipenija gidi.”
Bẹẹ ni Wolii Elijah sọ.