Iyawo mi ko dana ounjẹ fun mi lati bii ọdun meji sẹyin, o ni nitori mo n mugbo- Adeleke

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta 

Bi ibalopọ ṣe ṣe pataki ninu igbeyawo, bẹẹ naa ni ounjẹ gbigbọ latọdọ iyawo si ọkọ rẹ jẹ dandan. Ai dana ounjẹ iyawo fọkọ rẹ mọ ti mu baale ile kan torukọ ẹ n jẹ Adeleke Mejigbẹdu, gba kootu Ake lọ bayii, l’Abẹokuta, o si ti n beere fun ipinya laarin oun ati iyawo rẹ, Deborah Mejigbẹdu.

Nigba ti Ọgbẹni Adeleke n ṣalaye nipa ikọsilẹ to n beere fun naa, o sọ fun kootu lọsẹ to kọja pe ọdun keji ree ti iyawo oun ko ti dana ounjẹ foun mọ, to jẹ niṣe loun n daka jẹ.

Lori idi ti iyawo ko fi dana fọkọ rẹ mọ, Adeleke sọ pe

“ Ki i ṣe pe o wu mi lati kọ iyawo mi silẹ, obinrin daadaa to duro ti mi lasiko iṣoro ni. Igbo ti mo n mu pẹlu ọti lo ni ki n fi silẹ, ki n ma mu wọn mọ. Mo dẹ ti sọ fun un pe mi o le fi igbo ati ọti silẹ, oun kọ lo maa gba wọn lọwọ mi.

“Mo sọ fun un pe ko maa ni suuru pẹlu mi, ko yee ba mi ja nitori igbo ati ọti, ṣugbọn ko da mi lohun.

“O maa n ba mi ja lori awọn nnkan yẹn gan-an to jẹ ẹru maa n ba mi lati lọ sile ti mo ba ṣiwọ nibi iṣẹ ni. Nitori igbo ati ọti ti mo n mu ni ko ṣe dana ounjẹ fun mi mọ o, ọdun keji ree ti iyawo mi ko ti se ounjẹ fun mi mọ, ko dẹ si idi kankan ju nitori igbo ti mo n mu ati ọti yii naa lọ.

“ Oluwa mi, ẹ ba mi bẹ ẹ ko ma ba mi ja mọ. Ifẹ aye mi niyẹn, mo fẹran ẹ, ki i ṣe pe mo fẹẹ kọ ọ silẹ bẹẹ yẹn naa, ẹ kan ba mi bẹ ẹ ko yee ba mi ja nitori igbo ati ọti. Ẹ tun ba mi sọ fun un ko maa ṣe suuru diẹdiẹ, oun kọ lo maa ni ki n ma mugbo ati ọti mọ.”

Ninu awijare rẹ, Deborah to bimọ mẹrin fọkọ ẹ sọ pe irọ lọkọ oun n pa pe oun ko dana fun un fọdun meji. O loun maa n se ounjẹ fun un lasiko to yẹ.

“Oluwa mi, igbeyawo yii ti su mi, nitori awọn ọmọ mi ni mo ṣi ṣe duro sibẹ ti mi o kọ ọkọ mi yii silẹ. Ṣe ẹ ri ti igbo to n mu yẹn, mi o le fara da a mọ, bẹẹ naa lo dẹ tun n mu ọti, gbogbo ẹ lo ti su mi o. O su mi patapata ni.”

Nigba to sọrọ bayii, Aarẹ A.O Abimbọla to gbọ ẹjọ naa sọ pe oun yoo fun awọn mejeeji lasiko diẹ lati yanju ọrọ yii, nitori ohun to ṣee yanju ni.

Adajọ ni obi awọn mejeeji yoo da si ọrọ yii, yoo si yanju pẹlu ọrọ ajọsọ to fẹẹ waye naa.

O sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu kejila, ọdun 2021.

Leave a Reply