Adewumi Adegoke
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa niluu Igando, nipinlẹ Eko, ni obinrin aṣerun-lọṣọọ kan, Blessing Mormah, wọ ọkọ rẹ, David Mornah, lọ, to si bẹ adajọ kootu naa pe ki wọn tu igbeyawo ọdun mẹẹẹdọgbọn to wa laarin oun ati ọkunrin naa ka gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) ṣe sọ.
Ọkan ninu awọn ohun to n dun iyaale ile ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta naa ninu igbeyawo yii ni pe nnkan ọmọkunrin ọkọ rẹ ko ṣiṣẹ daadaa, o si ni oun ko le fara mọ iru eleyii. Obinrin yii ni nigba ti oun ṣakiyesi wahala naa, oun ni ko jẹ ki awọn lọ si ọsibitu, ṣugbọn ọkọ oun ko lo gbogbo oogun ti awọn dokita kọ fun un, o ni ko si nnkan kan to n ṣe oun. Bi mo ba si ni ko jẹ ka ṣe ere lọkọlaya, ‘kinni’ rẹ ko ni i ṣiṣẹ.
Yatọ si eyi, obinrin naa ni ki i ṣe pe ọkunrin yii kuku wu oun nigba toun fẹ ẹ, niṣe ni wọn fi dandan mu oun lati fẹ ẹ. Blessing ni baba oun lo fi tipa mu oun lati fẹ ọmọkunrin naa.
Iyaale ile yii ni gbogbo igba lawọn maa n ja, bawọn ba si ti ja bayii, ọkọ oun ki i ranti pe ede aiyede ki i ṣe ohun ti eeyan le fẹ iru rẹ ku ninu igbeyawo, kaka ki awọn si yanju wahala to ba wa laarin awọn, niṣe ni yoo sọ pe ki oun ko ẹru oun jade, ki oun maa lọ. Bẹẹ ni ko si tun ni ibọwọ fun awọn ẹbi oun.
Obinrin yii ni ija ojoojumọ ati bo ṣe maa n halẹ pe ki oun ko jade yii, ati ‘kinni’ rẹ ti ko ṣiṣẹ daadaa loun fi kuku ko jade kuro nile rẹ.
Blessing ni o ti to ọdun kan bayii ti oun ti ko kuro nile rẹ, nigba ti oun si wa nibẹ paapaa, ki i mojuto oun, oun atawọn ọrẹ rẹ ni wọn jọ maa n muti kiri.
Nidii eyii, ki adajọ fopin si igbeyawo naa ki kaluku maa ba tirẹ lọ.