Ko buru rara ki oloṣelu pin owo lasiko idibo, Buhari lo sọ ọ o

Aderounmu Kazeem

Aarẹ Muhammed Buhari sọrọ kan laipẹ yii, ohun to sọ ni pe ko si ohun to buru rara bi oloṣelu kan ba nawo daadaa fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo.

Lasiko ti Gomina Godwin Obaseki ti ipinlẹ Edo ati igbakeji ẹ. pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP kan, lọọ dupẹ lọwọ Aarẹ orilẹ-ede yii naa lo sọ bẹẹ.

O ni, o tẹ oun lọrun ki oloṣelu to ba lowo daadaa to fẹẹ na, pin in lọpọ yanturu fawọn araalu, nitori yoo ni bukata ti owo ọhun yoo gbọ ni kọrọ yara wọn. Ṣugbọn ohun to buru, ti ọkan oun si kọ, ni ki oloṣelu maa ko tọọgi jọ lati fi pa araalu, tabi pa ara wọn danu nitori ọrọ ibo didi lasan.

Pẹlu  awada lo fi sọ fun Obaseki pe oun dupẹ lọwọ ẹ to ko awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ẹ waa ki oun bo tilẹ jẹ pe niṣe ni wọn fidi APC oun janlẹ l’Edo. Obaseki naa dupẹ o: Gomina ọhun ni aṣaaju daadaa ni Buhari to fi oun lọkan balẹ pe ojooro kan bayii ko ni i si, ti ko si si ojooro ọhun loootọ.

Leave a Reply