Ko le ṣẹlẹ laelae, Amọtẹkun ko ni i si labẹ ijọba apapọ -Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, naa ti darapọ mọ awọn to sọ pe ala ti ko le ṣẹ ni ki ikọ Amọtẹkun wa labẹ ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina sọrọ naa lasiko to n ṣepade pẹlu gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ mejidinlaaadọrin to wa nipinlẹ Ọyọ. Makinde, ẹni ti Akọwe iroyin rẹ, Taiwo Adisa, gbẹnu rẹ sọrọ sọ pe ‘’Eto aabo jẹ ọkan ninu awọn afojusun ijọba yii, gbogbo ohun to ba wa nikaapa wa la si maa ṣe lati ri i pe eto aabo fun ẹmi ati dukia to fẹsẹ rinlẹ wa fun awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ. A si fẹ ki gbogbo wa sun, ka le han-an-run lai si ibẹru tabi ifoya kankan. Ipinlẹ Ọyọ jẹ ipinlẹ to tobi, to si paala pẹlu oriṣiiriṣii ilu, nitori naa la ṣe gbọdọ mu eto aabo ni pataki.

‘‘Laipẹ yii ti awọn adigunjale ṣọṣẹ niluu Okeho, awọn ọdẹ agbegbe naa ni wọn dide, ti wọn koju awọn oniṣẹ ibi naa. Awọn ni wọn fọ gbogbo inu igbo kaakiri, ti wọn si ri i pe ọwọ tẹ wọn.

Idi niyi ti mo fi n sọ ọ, ti mo n tẹnu mọ ọn, ti mo si n pariwo fun gbogbo aye pe mimi kan ko le mi ikọ Amọtẹkun, bẹẹ ni wọn ko ni i si labe akoso tabi idari ọga ọlọpaa ilẹ wa. Awa la oo maa dari rẹ, aabo awọn eeyan wa ṣe pataki si wa, nitori ko si aṣeyọri kankan ta a le ṣe nibi ti ko ba ti si aabo to daju.

Bakan naa ni gomina rọ awọn alaga ijọba ibilẹ yii lati pada si agbegbe wọn, ki wọn lọọ mojuto eto aabo ibẹ, ki awọn araalu le fẹdọ lori oronro. Makinde ni eto aabo jẹ ọkan pataki ninu ipenija ti ipinlẹ Ọyọ ni. O waa rọ awọn eeyan naa ki wọn lọọ da igbimọ alakooso eleto aabo silẹ lawọn ijọba ibilẹ wọn kaakairi ni kiakia, pẹlu ileri pe oun yoo ṣeto owo to yẹ lati ṣe atilẹyin fun wọn lati mu ki eleyii ṣeeṣe.

O waa kilọ fun awọn alaga naa pe bi ilu ati awọn agbegbe wọn ba ṣe lalaafia si, ti aabo to dara si wa nibẹ ni yoo sọ boya wọn yoo tun fa wọn kalẹ lati dije dupo tabi bẹẹ kọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: