Ko pẹ ti Sunday tẹwọn de lo tun lọọ jale ni Ketu

Faith Adebọla, Eko

 Ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Emmanuel Sunday, ṣẹṣẹ tẹwọn de laipẹ yii ni latari iwa adigunjale to hu, ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro tun ti ba a pada, nibi to ti n jale nirona lọwọ ni wọn ti mu un.

Owurọ kutu, ni nnkan bii aago mẹjọ, lawọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa, RRS, (Rapid Response Squard) ti wọn n ṣiṣẹ laarin Ọjọta si Ketu, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, nipinlẹ Eko, ṣakiyesi bi ọdaran naa ṣe duro pẹkipẹki pẹlu onimọto kan labẹ biriiji Ọjọta, bawọn ọlọpaa naa si ṣe n wo ohun to ṣẹlẹ lọọọkan, wọn ri i bi onimọto naa ṣe n ko foonu rẹ atawọn dukia kan fun Emmanuel pẹlu ibẹru-bojo. Eyi lo mu ki wọn fura, ti wọn si sun mọ wọn.

Tori p’awọn agbofinro naa ko wọṣọ, ọdaran yii ko tete fura ti wọn fi kan an lara, wọn si ri ibọn ilewọ to yọ si onimọto naa nibadi ẹ, ni wọn ba mu un.

Nigba to de teṣan Alapẹrẹ, Emmanuel jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun n digunjale, ati pe oun o ṣẹṣẹ bẹrẹ iwa ọdaran naa ni, bo tilẹ jẹ pe oun ti ṣẹwọn ri. Nigba ti wọn wo akọsilẹ, wọn ri i pe loootọ lawọn ọlọpaa teṣan Alapẹrẹ ti mu un ri, ti wọn foju ẹ bale-ẹjọ, ti adajọ si sọ ọ sẹwọn oṣu mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara. Ọgba ẹwọn Kirikiri lo ti lo saa ẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn taari afurasi naa si ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale, o ni ki wọn tete towe ọdaran yii, tori yoo tun kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ lẹẹkan si i.

Leave a Reply