Peter ni ohun kan ti maa n sọ pe koun bẹ sodo, afigba t’ọmọkunrin naa b’omi lọ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gende’kunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Peter Ajayi, ti dawati bayii lẹyin to bẹ sinu odo Asa, l’Opopona Unity, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ buruku yii ṣẹlẹ ti Ajayi sọ mọlẹbi rẹ sinu ibanujẹ. Gbogbo akitiyan ajọ panapana lati yọ oku rẹ jade ninu odo lo ja si pabo nitori wọn o ri i mọ.

Olugbe agbegbe Taiwo Isalẹ kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju, Olaiya, sọ fun oniroyin wa pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ niṣẹlẹ naa waye, nibi ti Peter ti sare jade lati inu ile rẹ, o sare lọ si eti odo, o bọ bata, o si so aṣọ mọ ori, lo ba bẹ somi. O tẹsiwaju pe o ti maa n sọ pe awọn kan n sọ fun oun pe ko lọọ pa ara rẹ, eyi lo mu ki awọn obi rẹ gbe e lọ si ṣọọṣi fun itusilẹ.

Ọlaiya ni iya rẹ lo n pariwo nigba to sare jade ninu ile to n sare lọ si odo, ṣugbọn awọn to fẹẹ ran iya naa lọwọ ko ri i mu to fi bẹ sodo.

Agbẹnusọ ajọ panapana ni Kwara, Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ l’Ojọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, o si ni gbogbo inu odo ni wọn ti wa kiri lati Opopona Unity, titi de agbegbe Shao, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ naa, wọn o ri oku arakunrin ọhun.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Ajayi, ṣugbọn wọn n gbe niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Iya rẹ sọ pe o ti to ọdun kan bayii ti wọn ti n fura si iṣesi si rẹ ko too lọọ bẹ sodo ninu ọsẹ yii.

Leave a Reply