Ko si agunbanirọ kankan laarin awọn mẹwaa ti ile wo pa l’Ebute-Mẹta– ileeṣẹ NYSC

Faith Adebọla, Eko

Ọrọ kan to n ja ranyin lori afẹfẹ pe ọdọmọbinrin agunbanirọ kan wa lara awọn to kagbako iku ojiji nibi ijamba ile alaja mẹta to wo lagbegbe Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko, lopin ọsẹ to lọ yii, ti ja si iroyin ẹlẹjẹ, ileeṣe agunbanirọ ilẹ wa, ẹka ti Eko, ti kede pe irọ ni, ko si ọdọ to n sin ilẹ baba wọn ninu iṣẹlẹ ọhun.
Atẹjade kan ti Oluṣe-kokaari ẹka ileeṣẹ National Youth Service Corps, l’Ekoo, Abilekọ Yetunde Bọlarinwa, fi lede lọjọ Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un yii, lori iṣẹlẹ naa sọ pe ọdọbinrin Adekẹmi Zainab Adekunle ti wọn n tọka si gẹgẹ bii agunbanirọ ọhun ki i ṣe agunbanirọ rara.
“Ninu iwadii ta a ṣe, ati gẹgẹ bii alaye ti ẹgbọn oloogbe naa ṣe fun wa, Oloogbe Adekẹmi Zainab Adekunle gboye jade ni ẹka imọ itan, ni Fasiti Tai Solarin University of Education, to wa ni Ijagun, n’Ijẹbu-Ode, ṣugbọn ko ti i wọṣẹ agunbanirọ, ko si ti i gba lẹta lati darapọ mọ wọn nigba ti ijamba yii fi waye.
“Adekẹmi ṣẹṣẹ n ṣe ọna bo ṣe maa gba lẹta lati fasiti naa, ki wọn le forukọ ẹ silẹ fun iṣẹ aṣesinlu to n bọ ni, ki iṣẹlẹ yii too ṣẹlẹ.
“A tun gbọ pe ọmọbinrin naa ṣabẹwo sawọn obi ẹ to n gbe ile naa lọwọ ni ijamba yii fi ka a mọ, to si doloogbe.
Ileeṣẹ NYSC kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yii, a si gbadura ki Ọlọrun tẹ wọn safẹfẹ rere.”
Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ni ile alaja mẹta ọhun to wa ni Ojule kejilelọgbọn, Opopona Ibadan, ni Ebute-Mẹta, ṣadede rọ lulẹ, owurọ ọjọ keji lawọn ẹṣọ panapana ati ti ileeṣẹ apapọ to n ri si ọrọ pajawiri, NEMA, (National Emergency Maintenance Agency) de ibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si doola ẹmi awọn ti ajalu naa ka mọ.
Ninu atẹjade kan ti ọga agba ileeṣẹ panapana fi lede, o ni eeyan mẹwaa lawọn hu oku wọn jade labẹ awoku ile ọhun, ọkunrin mẹfa, obinrin mẹrin ni wọn. Mẹrinlelogun lawọn eeyan ti wọn doola ẹmi wọn, ṣugbọn ọpọ ninu wọn lo wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri lọwọ, tori wọn ti fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii.
Margaret ni awọn ti wa gbogbo abẹ awoku naa de isalẹ, lati ri i daju pe ko si oku tabi alaaye kan to ṣẹku, wọn si ti ta okun di agbegbe naa mọ.
Bakan naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari ki kọminu si bawọn ile ṣe n wo, to si n fẹmi ọpọ eeyan ṣofo kaakiri orileede yii. Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹẹ rẹ feto iroyin, Fẹmi Adeṣina fi lede, Aarẹ daro pẹlu mọlẹbi awọn to doloogbe, o si paṣẹ fawọn ajọ to n ri si ile kikọ ati eto ilu, lati tubọ ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, ki iru jamba wọnyi le dohun igbagbe nilẹ wa.

Leave a Reply