Ọlawale Ajao, Ibadan
Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti pinnu lati na an tan bii owo pẹlu awọn ọta ẹ nidii oṣelu. O ni ko si atako tabi ibanilorukọ jẹ ti ẹnikẹni le ṣe ti yoo ni ki oun ma dupo aarẹ lọdun to n bọ.
Lasiko abẹwo to ṣe si Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ yan, Agba-Oye (Sẹnetọ) Lekan Balogun, nile ẹ to wa laduugbo Alarere, n’Ibadan, lo ti sọrọ naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Abẹwo ọhun ko ṣẹyin erongba Aṣiwaju Tinubu lati daarẹ orileede yii lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2023.
Ọkunrin to ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri yii fọwọ sọya pe, “Mo ṣetan lati di aarẹ orileede yii. Mo si ti kawe ọjọgbọn kan to sọ pe teeyan ba fẹẹ ba ẹlẹdẹ ja, oluwarẹ ni lati jọwọ ara ẹ silẹ fun idọti. Bo ti wu ki awọn eeyan dunkooko mọ mi tabi ba mi lorukọ jẹ to, ko si ohunkohun to le da mi duro lori ipinnu mi lati dupo aarẹ lasiko idibo ọdun 2023.
“Gbogbo awuyewuye to n ṣẹlẹ lasiko yii ko jẹ tuntun, gbogbo igba ti ẹya Yoruba ba ti n gbero lati daarẹ orileede yii lariwo maa n waye bẹẹ, ti awuyewuye yoo si gba gbogbo Naijiria kan.”
Nigba to n ki Olubadan tuntun naa ku oriire nipa bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo gori apere Olubadan laipẹ, Tinubu fi igbagbọ rẹ han pe asiko Sẹnetọ Balogun yoo tubọ mu igba oọtun de ba ilu Ibadan nitori pe Ọmọwe ni i ṣe, ati pe o tun jẹ oloṣelu to nifẹẹ ilọsiwaju ilu ẹ.
O waa ṣadura pe Eledua yoo fẹmi gigun ati alaafia pipe jinki ọba tuntun naa.
Sẹnetọ Balogun, pẹlu aburo ẹ ti oun naa tun jẹ sẹnetọ, Kọla Balogun, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ ni wọn jọ gba Tinubu atawọn ẹmẹwa ẹ lalejo. Oun naa lo si sọrọ lorukọ ẹgbọn ẹ ti ireti wa pe yoo jọba laipẹ yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ bayii, ẹni ta a nilo nipo aarẹ bayii lọmọ Yoruba to jẹ ẹni aye n fẹ, to si kunju oṣuwọn lati mu iṣọkan wa laarin awọn ẹya orileede yii pada.
“Loootọ, o le nira lati depo aarẹ o, ṣugbọn lagbara Ọlọrun, Aṣiwaju Tinubu ni yoo bori, ti yoo si rẹyin awọn ti wọn jọ n figagbaga.”
Lẹyin abẹwo ọhun ni Tinubu atawọn ẹmẹwa ẹ gba ilu Ọyọ lọ fun abẹwo si Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta laafin rẹ, nibi ti ori ade naa ti wure fun Tinubu pe awọn alalẹ yoo ti i lẹyin lati di aarẹ orileede yii.