Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bi abajade iwadii igbimọ to ri si iṣẹlẹ ENDSARS lọdun to kọja ṣe sọ pe ko din leeyan mẹsan-an tawọn ọlọpaa yinbọn pa ni Lẹkki lọjọ naa, Minisita eto iroyin, Alaaji Lai Mohammed, sọ pe bẹẹ kọ. O ni ko si ipaniyan rẹpẹtẹ kan to waye ni Lẹkki, aalọ lasan lawọn to sọ bẹẹ n pa.
Nibi ipade oniroyin to waye l’Abuja lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, ni Lai Mohammed ti sọ fawọn akọroyin, pe ayederu ati awuruju lasan ni abajade iwadii igbimọ tijọba Eko gbe kalẹ naa.
Lai sọ pe bii ẹni ko ọmọde jọ lasiko ere oṣupa, to si n paalọ irọ fun wọn ni.
Ṣe igbimọ ẹlẹni mẹsan-an to ri si iṣẹlẹ ifẹhonu han to waye logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, naa ti sọ pe ko din leeyan mẹsan-an tawọn agbofinro yinbọn pa ni Lẹkki Too-geeti tawọn ọdọ naa ti fẹhonu han lọjọ yii.
Wọn ni awọn ọmọ to n fẹhonu han ko ba tija wa, asia orilẹ-ede Naijiria ni wọn mu dani, orin orilẹ-ede Naijiria ni wọn n kọ, ti wọn jokoo jẹẹjẹ wọn lẹnu ọna abawọle si Too geeti naa. Ṣugbọn ikọ ọlọpaa de, wọn ṣina ibọn bolẹ lai beṣu-bẹgba, oku si sun lọjọ naa ni Lẹkki, oku awọn alaiṣẹ to n fẹhonu han pe ki SARS maa lọ si ni.
Koda, iwe oloju-ewe ọọdunrun ati mẹsan-an (309) ni wọn fi kọ abajade iwadii naa, ninu ẹ ni wọn si ti ṣalaye iku awọn eeyan to doloogbe naa bii ipaniyan rẹpẹtẹ( massacre).
Gomina Babajide Sanwo-Olu to tẹwọ gba abọ iwadii naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti gbe igbimọ mi-in kalẹ ti yoo tun ṣagbeyẹwo esi yii, ti wọn yoo si gbe e lọ sọdọ awọn ti yoo gbe igbese lori ẹ.
Ṣugbọn minisita eto iroyin, Lai Mohammed, sọ pe eremọde lasan ni gbogbo eyi ti wọn n ṣe yii, ko si ipaniyan abaadi ni Lẹkki rara.