Ko si iwọde kankan mọ lEkoo, ẹni ta a ba mu, janduku ni – Ileeṣẹ ọlọpaa lo sọ ọ

Aderounmu Kazeem

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, ti ke si awọn ọdọ to bẹrẹ iwọde tako ajọ ẹṣọ agbofinro SARS ki wọn jade sita bayii lati sọ pe awọn ti sinmi iwọde.

Lori eto kan to waye lori redio laaarọ yii nibi ti wọn ti ba a sọrọ lori foonu ẹ lo ti sọrọ ọhun. O ni, “Ni bayii, ohun to foju han ni pe, awọn janduku kan ti ja a gba mọ wọn lọwọ. Ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe iwọde mọ, o ti lọwọ janduku ninu. Bii teṣan ọlọpaa mẹrindinlogun ni wọn ti jo nina kaakiri ipinlẹ Eko.

“Bi wọn ti ṣe n dana sunle iṣẹ nlanla, bẹẹ ni wọn kọlu awọn ileeṣẹ iwe iroyin, ti wọn n pa ọlọpaa. Wọn lawọn n ja fun awa ọlọpaa, ki ijọba ṣatunṣe lori owo oṣu wa, bẹẹ ni wọn n kọlu teṣan ̀ọlọpaa, ti wọn tun n pa ọlọpaa paapaa, ọrọ yẹn wa da bii o n ṣe mi, o n gba mi.

“Nipinlẹ Eko bayii, ko si ohun to n jẹ iwọde mọ, oju ti awa ọlọpaa fi n wo o niyẹn. Iwa janduku lo ku, yoo si dara ti awọn ti wọn da a silẹ ba le bọ si gbangba ki wọn sọ pe awọn ti dawọ ẹ duro ni tawọn, ki ọlọpaa le mọ awọn ti oun yoo koju.”

Adejọbi fi kun un pe nibo ni eeyan ti n ṣe iwọde ti wọn n fọ banki, ti wọn n dana sun teṣan ọlọpaa, ti wọn n ji ibọn ọlọpaa gbe sa lọ.

Lana-an ode yii ni wahala ọhun gbọna mi-in yọ lẹyin ti awọn ṣoja kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde ni too-geeti ni Lẹki, nibi ti wọn ti yin wọn nibon lalẹ ijẹta. Nigba ti ilẹ si mọ, bo ṣe di pe lara awọn to n ṣe iwọde yii bẹrẹ si i sọna si ileeṣẹ, ti wọn n dana sun agọ ọlọpaa, tọrọ ọhun si burẹkẹ gan an niyẹn.

Leave a Reply