Jọkẹ Amọri
Arẹwa oṣere ilẹ wa to maa n kopa onijangbọn ninu ere, tawọn eeyan si fẹran rẹ daadaa nni, Wumi Toriọla, ti sọ pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun ati ọkọ oṣere ẹgbẹ ẹ, Toyin Abraham. Oṣere naa ni ati eyi to kọkọ fẹ o, iyẹn Adeniyi Johnson, ati eyi to wa lọọdẹ rẹ bayii, Kọlawọle Ajeyẹmi.
Ohun to fa ọrọ yii ko ju ọrọ kan ti ọkan ninu awọn oniroyin ori ayelujara ti wọn n pe ni Gistlover gbe jade nipa oṣere naa pe oun ati ọkọ Toyin jọ n gbọ iṣẹ ara wọn wo ni kọrọ, ati pe Toyin ka a mọ, oṣere naa si ti tọrọ idariji.
Ṣugbọn Wumi ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara, o ni awọn eeyan kan ni wọn duro ibajẹ, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ba oun lorukọ jẹ, ṣugbọn Ọlọrun to gbe oun soke ko ni i ja oun walẹ, bẹẹ ni ko ni i gba fun awọn aṣebajẹ naa lati ba orukọ ti oun ti n fi ọpọlọpọ ọdun gbe duro bajẹ.
Ninu ọrọ kan ti oṣere naa kọ to ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lori Instagraamu rẹ lo ti sọ pe oun ko ni i da ẹnikẹni lohun, bẹẹ ni oun ko ni i fesi si irọ yoowu ti ẹnikẹni ba pa nipa oun lati oni lọ mọ. O ni esi ti oun n fọ si ẹsun irọ ti wọn fi kan oun yii ni yoo jẹ igba ikẹyin ti oun yoo da ẹnikẹni loun. O ni ohun to ba wu ẹnikẹni ko fi ẹnu rẹ sọ nipa oun, iṣẹ oun ati bi aye oun yoo ṣe daa lo ku ti oun maa gbaju mọ.
Eyi ni ohun ti Wumi kọ: ‘Aarọ yii ni ẹnikan pe akiyesi mi si ọrọ buruku kan ti ẹnikan kọ sori ikanni Gistlover pe ọkọ ọkan ninu awọn oṣere ẹgbẹ mi n ba mi sun.
‘‘Ki i ṣe pe ọrọ yii jẹ irọ nikan, o jẹ ọrọ buruku, ọrọ ibi, ti wọn n ṣọ lati ba orukọ mi jẹ.
‘‘Ki i ṣe pe mi o ni ajọṣepọ pẹlu ọkọ ẹni ti wọn n sọ yii nikan kọ, mi o ni ajọṣepọ kankan pẹlu ọkọ to ti kọkọ fẹ paapaa. Mi o mọ idi ti awọn alatilẹyin oṣere yii fi fẹran lati maa ba orukọ mi jẹ kiri, ki wọn si maa da wahala silẹ laarin wa. Ṣugbọn ohun ti mo mọ ni pe eyi ni yoo jẹ igba ikẹyin ti mo maa fesi lori ohunkohun to ni i ṣe pẹlu ẹni ti a n sọrọ rẹ yii.
‘‘Mo ti tẹsiwaju nipa igbesi aye mi. Ọjọ iwaju mi nikan lo jẹ mi logun ti mo n wo bayii, ki n si tun maa gbe ere jade. Ki n tiẹ ranti sọ fun yin, iṣẹ ti mo n po pọ lọwọ fun yin ni Queen Latifa lọna to tun ga ju ti tẹle lọ. Lori rẹ ni mo si maa lo gbogbo agbara mi si, ki i ṣe ki n maa da awọn ti wọn ko ni ero mi-in lọkan ju ki wọn maa wa bi wọn yoo ṣe fa mi walẹ lọ, ti wọn si n wa iṣubu mi.
Mi o ni i ṣubu, bẹẹ ni mi o ni i ja kulẹ, niwọn igba ti Ọlọrun wa lori itẹ. Ọlọrun nikan ni alagbara, oun nikan naa ni n oo si maa gbe ẹmi mi le ni gbogbo igba’’.
Bayii ni Wumi pari ọrọ rẹ.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n da si ọrọ naa, ti wọn si n naka abuku si Toyin Abraham ati awọn alatilẹyin kan pe eku wẹrẹ jẹle ni. Wọn ni ọpọ igba ni Toyin maa n dẹ awọn alatilẹyin rẹ si awọn oṣere ẹgbẹ ẹ to ba ni ede aiyede pẹlu, tabi ti ko ba fẹran, to ba si ti ṣe eleyii ni yoo mori mu, ti yoo si tun maa ba tọhun kaaanu, ti awọn eeyan ko si ni i mọ pe oun lo wa nidii jamba naa.
Tẹ o ba gbagbe, ija nla kan ti kọkọ ṣẹlẹ laarin Toyin ati Wumi Toriọla. Ija Ṣeyi Ẹdun to ṣẹṣẹ bi ibeji laipẹ yii ni Wumi n gbe nigba naa pẹlu bi Toyin ṣe fungun mọ ọn, to si fẹsun kan kan pe o ti n fẹ ọkọ oun tẹlẹ, iyẹn Adeniyi Johnson ko too di pe oun ko jade nile rẹ.
Ija yii ni Wumi gba kanri, to si n gbeja Ṣeyi Ẹdun, ti awọn mejeeji si jọ n ba Toyin ja.
Ṣugbọn lẹyin ọdun diẹ ti ọrọ yii ṣẹlẹ, tirela gba arin Wumi ati Ṣeyi kọja, awọn mejeeji ko sọrọ sira wọn mọ. Asiko naa ni Toyin ati Wumi tun di ọrẹ pada, ti wọn si jọ n bara wọn ṣe. Eyi lo mu ki Toyin pe Wumi si ere rẹ kan to ṣe nigba naa.
Laipẹ yii ni wọn ni Toyin fi Wumi ṣe yẹyẹ lori bi oun ati ọkọ rẹ ṣe kọ ara wọn silẹ, ti inu rẹ ko si tun dun si bi Wumi ṣe lọọ ba Funkẹ Akindele ṣere ninu fiimu rẹ, ‘Battle on Buka Street’ ti wọn lo n ta daadaa ju eyi ti Toyin ṣe, ‘Ijakumọ’ lọ lọja bayii.
Gbogbo awọn nnkan yii wa lara ohun ti wọn lo n kan an lara si Wumi. Ṣugbọn ki i saaba ba eeyan ja taara, awọn kan ni yoo ran ti wọn yoo maa ba ẹnikẹni to ba fẹẹ kọ lu lorukọ jẹ gẹgẹ bawọn to mọ ọn ṣe sọ.
O jọ pe Wumi Toriọla fura si eleyii lo fi gbe fidio kan jade laipẹ yii pe ki wọn yee parọ mọ oun, ki wọn yee ba oun lorukọ jẹ, ki ọn si yee maa sanwo fun awọn eeyan lati gbe awọn ọrọ ti oun ko sọ nipa awọn oṣere ẹgbẹ oun jade lori ayelujara. Ẹkun ni ọmọbinrin naa bu si, to si n ṣepe rabandẹ rabandẹ, fun awọn to fura si pe wọn n ṣe eleyii, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ wọn.
Nibi to ka a lara de, o ni ẹnikẹni to ba ri oun pẹlu baba alaye kan, tabi ẹnikẹni ninu awọn oṣere ẹgbẹ oun to ba gbe oun fun baba alaye kan gẹgẹ bi ọpọ ninu wọn ṣe maa n ṣe fun ara wọn le jade ko waa wi. Bẹẹ lo pe awọn ọkunrin paapaa nija pe baba alaye ti oun ba ti ba ṣe ri le yọju sita.
Ọpọ awọn to n sọrọ nipa iṣẹlẹ yii ni wọn n naka aleebu si Toyin, ti wọn si n sọ pe ko yẹ ki agbalagba rẹ maa ṣe langba langba, bẹẹ ni ko yẹ ko maa gbe inu okunkun tafa soke si awọn ẹlẹgbẹ rẹ nitori lọjọ to ba dẹkun biba awọn ẹlẹgbẹ rẹ jẹ ni wọn yoo bẹrẹ si i ba oun naa jẹ.
Bakan naa lawọn eeyan n bu ẹnu atẹ lu ija ojoojumọ to n waye laarin awọn oṣere Yoruba yii, ti awọn mi-in si n sọ pe ọpọ wọn ki i ṣe awokọsẹ rere bii ti i wu ko ri.
Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, Wumi ti ni oun ko ni i da ẹnikẹni loun mọ o, o ni ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fẹnu rẹ sọ, iṣẹ oun lo ku ti oun ma gbaju mọ bayii, oun ko raaye ahesọ tabi ẹjọ wẹwẹ kankan.