Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Oluwoo ti ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe irọ to jinna soootọ ni ọrọ ti awọn kan maa n sọ pe Ifa lo n yan ọba nilẹ Yoruba.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ iwe iroyin kan laipẹ yii ni Ọba Akanbi ti sọ pe awọn gomina ni wọn n yan ọba, ẹni ti wọn ba si ti yan ni Olodumare n fọwọ si.
Oluwoo ni, “Ẹ sọ fun mi, ọba kan ti Ifa mu nilẹ Yoruba. Ẹni ti gomina ba mu ni Ọlọrun ti yan lati jẹ ọba. Ko si ọba kankan nilẹ Yoruba ti yoo sọ pe Ifa mu oun.
“Nigba ti gomina ba ti mu ọ tan lo too di ọba. Ifa ko ni agbara kankan lori gomina. Koda, laye awọn baba nla wa, ẹni to ba lagbara ju lọ ni wọn fi maa n jọba.
“Nigba ti emi fẹẹ jẹ ọba, mi o mọ gomina, nitori mo ṣẹṣẹ de lati orileede Canada ni, ṣugbọn mo sọ fun awọn ti a jọ n du oye nigba naa ti wọn ni owo ju mi lọ pe koda bi wọn mọ Barack Obama tabi gomina, emi ni ma a jọba.
“Mi o ri gomina titi di alẹ ọjọ ti wọn fẹẹ kede orukọ mi gẹgẹ bii ọba. Aago kan idaji ni mo ri i, ohun gbogbo si pari. Iṣẹ Olodumare ni, Ọlorun awa Yoruba, Ọlọrun awọn baba wa, ko sẹni to le ye. Nigba ti Ọlọrun ba fi eeyan jẹ ọba, o ni idi kan pato.”