Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Imo, Ọgbẹni Hope Uzodinma, ti ni bi eto idibo gbogbogboo to maa waye lọdun 2023 nilẹ wa ko ba lọwọ kan eru ninu, oun o ri idi ti ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressive Congress) ko fi ni i jawe olubori, tori akiyesi toun ṣe ni pe awọn eeyan nifẹẹ bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe n ṣejọba yii, wọn n gboṣuba gidi fun un ni.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nileejọba ipinlẹ Imo, l’Owerri, lo sọrọ naa lỌjọruu, Wẹsidee.
O ni ojoojumọ ni iye awọn to n di ọmọ ẹgbẹ APC kaakiri orileede wa tubọ n pọ si i, ọgọọrọ awọn eeyan lo si ti ṣetan lati tun dara pọ.
“Ki lo n ṣẹlẹ tabi to fẹẹ ṣẹlẹ ti ko ni i jẹ ki ẹgbẹ APC yege? Ṣe ẹ fẹẹ lẹ o mọ pe ipinlẹ mejilelogun ni APC n ṣakoso rẹ lọwọlọwọ yii ni?
Ẹ jẹ ki n soootọ fun yin, ero tawọn eeyan ni nipa iṣejọba Buhari ni pe Aarẹ n ṣe daadaa gidi, ta a ba yọwọ wahala eto aabo to ti d’ogun kaakiri aye, ati ajakalẹ arun COVID-19 to n ja bii iji kiri gbogbo ilu kari aye, sibẹ, Buhari ko Naijiria yọ lọwọ ojojo to n ṣe ọrọ-aje wa.
Tori naa, ọkan mi balẹ. Inu mi dun pe ọmọ ẹgbẹ APC ni mi, mo si ro pe a maa sa gbogbo ipa wa lati jẹ kawọn eeyan tubọ nigbẹkẹle ẹgbẹ wa, a o si ni i ja wọn kulẹ.”
Bẹẹ ni Uzodinma sọ.