Ko sohun to buru ninu ki aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ Musulumi – Fọlarin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo jẹ ki eto aabo mẹhẹ nipinlẹ Ọyọ, nitori to fi awọn tọọgi sipo, to si tun ro wọn lagbara.

Igbagbọ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC), Sẹnitọ Teslim Fọlarin, niyi igba to n kopa nibi eto ayajọ ọsẹ ẹgbẹ awọn oniroyin, iyẹn Nigeria Union of Journalists (NUJ), ipinlẹ Ọyọ, nile ẹgbẹ wọn to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, yii.

Gẹgẹ bi ọkunrin to n ṣoju ẹkun idibo Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣòfin agba niluu Abuja ṣe sọ, “Loootọ, ibi gbogbo ni wọn ti n ji eeyan gbe lorileede yii. Ṣugbọn nigba tẹ ẹ ba fi ẹni ti ko kawe ṣe olori ileeṣẹ tabi ajọ kan, ki lẹ n reti lati ọdọ iru ẹni bẹẹ. Nigba ti Ajimọbi n dupo gomina, o sọ pe oun ko ni i faaye gba awọn tọọgi, o si duro ti adehun to ṣe loootọ. Iyẹn niluu ṣe lalaafia, ti ko saaye fawọn tọọgi lati maa dalu ru lasiko ijọba rẹ.

Ṣugbọn nigba ti Ajimọbi lọ, ijọba yii fi tọọgi ṣe olori ileeṣẹ, wọn n fa posita ya, wọn n ti wo aworan ipolongo awọn oloṣelu wo lulẹ, wọn n ṣe awọn eeyan leṣe kaakiri igboro. Ohun to waa ya ni lẹnu ni pe ko si posita PDP kankan ti wọn fa ya. Iyẹn lẹ ẹ fi mọ pe awa (APC) bọwọ fun ofin, a si gba alaafia laaye.

“A n reti ki ẹyin oniroyin ni igboya lati maa sọ ododo nigba gbogbo. Bi ijọba ba n yan awọn ti ko kawe atawọn tọọgi sipo, o yẹ kẹ ẹ le maa fi iroyin yin pe wọn nija”.

Nigba to n sọrọ lori bi oludije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ṣe jẹ Musulumi, ti Sẹnitọ Kashim Shettima, to fẹẹ ṣe igbakeji ẹ naa tun jẹ Musulumi, Fọlarin, to tun jẹ Aṣiwaju Olubadan ilẹ Ibadan, sọ pe ko si ohun to buru ninu eto naa.

Gẹgẹ bii awijare ẹ, “Awa oloṣelu mọ ba a ṣe maa n fi oṣelu tayo. A  ti ṣe e ri laye M.K.O. Abiọla ati Gingibe, wọn wọle gbọọrọgbọọrọ. Musulumi (Babangida) lo wọgi le e. O gbegi dina mọ awọn Musulumi lati depo, ọ si gbe e fun Kirisitẹni (Ṣonẹkan). Awọn ọmọ Naijiria ko binu nigba naa nitori a ki i ṣe ijọba tabi oṣelu ẹlẹsinmẹsin lorileede yii.

Ara ohun to fa iṣoro wa ni Naijiria ni pe agbara ti ofin gbe wọ ijọba apapọ ti pọ ju. Tẹ ẹ ba ni wura ninu ilẹ ni ipinlẹ yin, wura yẹn ko wulo fun yin, dukia ijọba apapọ ni. Ijọba ipinlẹ kan ko lagbara lori eto aabo ara rẹ, ko si yẹ ko ri bẹẹ. O yẹ ki wọn fun ipinlẹ naa lagbara lati ni ọlọpaa tiwọn lati maa pese eto aabo to peye. Ara ohun ti Aṣiwaju Tinubu n fọnrere kiri niyẹn.

Inu wa dun pe Tinubu n dupo aarẹ, a si nigbagbọ pe o maa ṣe e daadaa”.

Ṣaaju l’Ọmọwe Tade Oludayọ, olukọ onipo giga ni Fasiti Ibadan (University of Ibadan), ninu idanilẹkọọ ẹ, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn tọọgi ṣe maa n fa iwe ipolongo ibo awọn oloṣelu ya.

Ninu Idanilẹkọọ ọhun to pe akọle ẹ ni “Gbigba Naijiria Silẹ Lọwọ awọn to Ji I Gbé”,  Ọmọwe Oludayọ sọ pe gbogbo ọmọ orileede yii lo ni ọna kan tabi omi-in ti wọn fi n pa idagbasoke orileede yii lara.

Ninu ọrọ tiẹ, Alaga ẹgbẹ NUJ ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ademọla Babalọla, rọ awọn oloṣelu lati maa fọnrere ohun ti wọn ba ni lati ṣe fun araalu lasiko ipolongo ibo, dipo ki wọn maa lo awọn tọọgi lati doju ija kọ awọn alatako wọn.

 

Leave a Reply