Ko sohun to kan ọga ọlọpaa patapata lori agbekalẹ ikọ Amọtẹkun -Oyelẹyẹ

 Awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba ti fohun ṣọkan labẹ ajọ kan ti wọn n pe ni Development Agenda for Western Nigeria Commission (DAWN), pe awọn ko fara mọ igbesẹ ti ijọba apapọ fẹẹ gbe lori ikọ Amọtẹkun ti wọn sọ pe yoo wa ni idari Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Mohammed Adamu.

Ọga Agba ileeṣẹ naa, Ṣẹyẹ Oyelẹyẹ lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kanfi sita. O ṣalaye pe awọn ileegbimọ aṣofin to wa ni ipinlẹ mẹfẹẹfa to jẹ ti ilẹ Yoruba ti ṣe agbekalẹ ofin ti yoo maa ṣatọna ikọ Amọtekun. Eyi ti ileeṣẹ Aarẹ n wi pe yoo wa labẹ idari ọga ọlọpaa patapata ko jọ ọ rara, afi to ba fẹẹ sọ pe aṣe ọga ọlọpaa lagbara ju ofin ti wọn ba ṣe ni ipinlẹ lọ nikan lo ku.

‘‘Ofin ipinlẹ, eyi ti awọn gomina ipinlẹ kọọkan fọwọ si lo n dari ikọ Amọtẹkun, pe wọn si sẹ idasilẹ ọlọpaa agbegbe ko yẹ ko papọ mọ iṣẹ ti awọn Amọtẹkun n ṣe tabi ko di i lọwọ.’’

Oyelẹyẹ ni bi ipinlẹ kọọkan ba ti waa gbe ofin kalẹ lori ọrọ Amọtẹkun, ko si ohun ti ẹnikẹni yoo tun maa ka owu sẹyin nipa rẹ mọ, nitori ipinlẹ kọọkan lo lagbara labẹ ofin lati ṣe agbekalẹ eto aabo fun awọn eeyan wọn, niwọn igba ti wọn ba ti fi ofin gbe e lẹsẹ, eyi ti awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba yii ti ṣe.

Ọga awọn DAWN yii ni ‘Niṣe ni awọn aṣofin lawọn ipinlẹ yii yoo jokoo sibi kan, ti wọn yoo si maa fi ijọba ṣe yẹyẹ lori aṣẹ onikumọ yii pe alagbara kan yoo jokoo siluu Abuja, yoo maa paṣẹ fun ikọ alaabo ti ijọba ipinlẹ ba gbe kalẹ. Ki waa ni anfaani pe awọn aṣofin gbe aba naa dide, ti gomina si fọwọ si i lati di ofin, to ba jẹ pe ọga ọlọpaa patapata ni yoo maa dari wọn.’’

Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Akọwe iroyin ati ikede fun ileeṣẹ Aarẹ, Sheu Garba, sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels pe gbogbo ẹṣọ alaabo ti wọn ba gbe kalẹ, ibaa ṣe ọlọpaa ibilẹ, Amọtẹkun ni o, tabi eyi yoowu ko jẹ, awọn eeyan agbegbe naa ni yoo maa ṣe e, ṣugbọn labẹ idari eto ti ọga ọlọpaa ilẹ wa ba gbe kalẹ ni wọn yoo ti maa ṣiṣẹ wọn. Ọga ọlọpaa patapata ni yoo si maa dari wọn.

Bakan naa lo fi kun un pe ọlọpaa agbegbe ti ijọba apapọ fẹẹ da silẹ ko ni i yatọ kaakiri ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa nilẹ wa, ijọba ko si ni i fara mọ ohunkohun ti ko ba ti ba ilana ijọba apapọ mu lori eleyii.  

One thought on “Ko sohun to kan ọga ọlọpaa patapata lori agbekalẹ ikọ Amọtẹkun -Oyelẹyẹ

Leave a Reply