Adewale Adeoye
Olori ẹgbẹ ajijangbara kan ti wọn n pe ni ‘Indigenous People Of Biafra’ (IPOB), Mazi Nnamdi Kanu, ti sọ pe ko sohun naa to le di idasilẹ orileede Biafra tawọn n ja fun lọwọ rara.
Lori ẹrọ ayelujara abayẹfo Tuita rẹ ni ọkan lara awọn lọọya rẹ, Aloy Ejimakor, ti gbe ọrọ naa jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii. Ọkunrin naa ni ko sohun naa to le di awọn lọwọ ki idasilẹ orileede Biafra ma ṣe wa si imuṣẹ gẹgẹ b’awọn kan ṣe n gbero rẹ.
Ninu ọrọ to gbe jade naa ni Kanu ti dupẹ gidi lọwọ gbogbo awọn ojulowo ọmọ ẹyin rẹ lori bi wọn ṣe n mule duro de e lakooko ti ko fi si nile bayii, ati bi wọn ṣe n ṣohun gbogbo pẹlu eto.
Kanu ni, ‘‘Inu mi dun gan-an si ẹyin tẹ ẹ pe ara yin lojulowo ọmọ ẹgbẹ IPOB, tẹ ẹ ṣi n ṣohun gbogbo pẹlu eto, ti ẹ ko jẹ ki wahala kankan ṣẹlẹ rara laarin ilu pẹlu bawọn alaṣẹ ijọba orileede yii ṣe fọwọ lile mu mi, ti wọn si fi mi pamọ satimọle lọna aitọ. Mo fẹẹ fi da yin loju pe ko sohun naa, to le di ipinnu wa lati gba ominira orileede Biafra lọwọ awọn alaṣẹ ilẹ yii bi akooko ba to.’’
Bẹ o ba gbagbe, lati ọdun 2021 ni awọn alaṣẹ ijọba orileede yii ti lọọ fọwọ agbara mu Kanu wa sorileede wa lati ilẹ Kenya lọhun-un, ti wọn si ju u satimọle awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS) kan to wa niluu Abuja. Latigba naa ni Kanu ti n ṣẹwọn lọdọ ijọba orileede yii.
Igba kan tiẹ wa to jẹ pe, kootu giga kan niluu Abuja dajọ pe ki wọn ju Kanu silẹ, ṣugbọn awọn alaṣẹ ijọba ilẹ wa taku pe ko sohun to jọ ọ, ti wọn si tun pẹjọ mi-in siluu Abuja bayii.
Aimọye awọn eeyan jankan-jankan nilẹ yii ati loke okun ni wọn ti n sọ pe kijọba ju Kanu silẹ, ṣugbọn ti wọn kọ jalẹ.
Bakan naa lo jẹ pe oniruuru ẹgbẹ aladaani paapaa ni wọn ti n rawọ ẹbẹ si Aarẹ Tinubu pe ko ṣiju aanu wo Kanu lọgba ẹwọn to wa, ko ju u silẹ.