Faith Adebọla, Eko
Ọlajide Balogun lorukọ ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji to wa ninu fọto yii, ọmọ bibi Akoko, nipinlẹ Ondo, ni, ṣugbọn beeyan ba ri bo ṣe ko oriṣiiriṣii foonu igbalode Android sọwọ, tọhun yoo ro pe oniṣowo foonu kan ni, bẹẹ oun kọ lo ni wọn o, jiji foonu ati jija foonu gba lafurasi ọdaran yii sọ di iṣẹ gidi l’Ekoo.
Ṣugbọn baalẹ awọn ‘ọmọ jagba’ yii, iyẹn orukọ tawọn adigunjale to yan jiji foonu ati jija foonu gba lọwọ awọn ero to kọja nirona maa n pe ara wọn, ti wa lakolo ọlọpaa, awọn agbofinro ikọ ayara-bii-aṣa lo gba a mu nibi to ti n ṣiṣẹẹbi e lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.
Bawọn ọlọpaa ṣe wi, wọn ni inu mọto tawọn fi n ṣe patiroolu lawọn wa loju ọna Ṣaṣa, lagbegbe Alimọṣọ, nipinlẹ Eko, lawọn fi taju kan-an ri afurasi ọdaran naa, o jokoo sẹyin ọlọkada kan to n gbe e lọ niwaju, afi para ti wọn ri Balogun to ṣadeede ja foonu gba lọwọ ọmọbinrin kan to n gba ipe lọwọ bo ṣe n rin lọ, lọmọbinrin ọhun ba figbe ta, ṣugbọn ọlọkada to gbe jagunlabi ti ṣina bolẹ.
Bawọn ọlọpaa yii ṣe ri i ni wọn gba fi ya wọn, nigba ti sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọna naa si fẹẹ ṣediwọ ni wọn bẹ silẹ ninu mọto wọn.
Ṣugbọn ara fu ọlọkada naa ati Balogun, wọn ni niṣe loun naa fo danu lori ọkada, o n sa lọ, kawọn ọlọpaa too le e mu, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e, bo tilẹ jẹ pe wọn o ri ọlọkada to gbe e, iyẹn sa lọ rau ni tiẹ.
Ni teṣan wọn, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Adekunle Ajiṣebutu, ṣe wi, o ni Balogun ti jẹwọ pe loootọ loun n jale, ṣugbọn ko ti i ju oṣu mẹjọ lọ toun bẹrẹ si i ja foonu gba. O tun sọ fun wọn pe ọkunrin kan to n jẹ Emeka loun maa n ta awọn foonu naa fun ni ọja kọmuputa ti wọn n pe ni Computer Village, n’Ikẹja. O ni ẹya foonu Android loun saaba maa n fẹ lati ji, tori o maa n rọrun lati pa kadara ẹ da, ki wọn le tete ri i ta l’ọja ti wọn ti n ta ẹru ole.
Nigba ti wọn yẹ ara ẹ wo, foonu igbalode Android marun-un ni wọn ba lọwọ ẹ, o loun ṣẹṣẹ ja awọn yẹn gba ni.
Ṣa, Ajiṣebutu ni awọn ti taari afurasi ọdaran naa sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, wọn lo ti n ran wọn lọwọ lati mọ bi wọn yoo ṣe ri ọlọkada to gbe e, ati Emeka, pẹlu awọn tọrọ naa tun kan, mu.
Lẹyin iwadii ni wọn maa fi wọn ṣọwọ sile-ẹjọ.