Faith Adebọla, Eko
Lẹyin ọdun mejilelogun iku baba rẹ, Kọlawọle, ọmọ bibi agba oṣelu ati oniṣowo ilẹ wa to ti doloogbe nni, Moshood Kaṣimaawo Ọlawale Abiọla, ti kede pe oun maa jade dupo aarẹ orileede wa lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023 yii.
Kọla fi erongba rẹ han l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin yii, ni olu-ile ẹgbẹ oṣelu People’s Redemption Party, PRP, niluu Abuja.
Akọbi MKO Abiọla ọhun ni:
“Mo sami si oni yii gẹgẹ bii ọjọ ti mo tun pada sidii oṣelu, lẹyin ọdun mẹtadinlọgbọn ti mo ti takete.”
“Mo diidi yan lati pada sidii oṣelu labẹ asia ẹgbe PRP ni, o si lawọn idi kan ti mo fi pinnu bẹẹ.
“Mo wo itan Naijiria, pe ẹgbẹ oṣelu wo la le sọ pe o wa fun Naijiria ni ti gidi. Mo ti ṣe gbogbo akiyesi, mo si ri i pe ẹgbẹ oṣelu to lọjọ lori ju lọ ni PRP, oun lo ṣi rọ mọ gbogbo ilana ati alakalẹ eto ijọba awa-ara-wa bo ṣe yẹ ko ri ni Naijiria.
“Awọn eeyan ti wọn nifẹẹ ara wọn denu lo pilẹ ẹgbẹ naa, ẹgbẹ ti eto oṣelu aarin ẹgbẹ wọn fẹsẹ rinlẹ ni.
“Mo pada sinu ẹgbe PRP lati fihan awọn ọmọ Naijiria pe igba kan ti wa ri ti Naijiria n ṣe nnkan daadaa, ti nnkan si n lọ daadaa fun wa, ko too di pe awọn eeyan tuntun kan dide, ti wọn o si ranti mọ pe Naijiria ti ṣe daadaa ri.”
“Ti mo ba lanfaani lati ṣoju awọn ọdọ ninu eto idibo aarẹ to n bọ, Naijiria tun gbọdọ bẹrẹ si i ṣe daadaa, bii tatijọ, yoo si daa ju bẹẹ lọ pẹlu,” gẹgẹ bo ṣe wi.