Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọga agba ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ gbe de ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Vivian Onadeko ti bẹrẹ iṣẹ, o ni ko ni i saaye fun iwa ọdaran lasiko toun.
CP Onadeko, to jẹ akọkọ obinrin ti yoo jẹ ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ lo gba ipo lọwọ CP Joe Nwackukwu Enwonwu ti wọn ṣẹṣẹ gbe kuro ni ipinlẹ naa, to si fa gbogbo akoso ọfiisi ọhun le obinrin naa lọwọ lọkọ Ẹtì, Furaidee, to kọja.
Ninu ọrọ àkọ́sọ rẹ lọfiisi lo ti sọ pe aabo ẹmi ati dukia gbogbo ara ipinlẹ yii lafojusun to ṣe pataki ju lọ soun.
O ni lati jẹ ki afojusun yii wa si imuṣẹ, awọn araalu paapaa ni lati kopa tiwọn nipa pẹlu fifọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn agbofinro lati maa tete ta awọn ọlọpaa lolobo ṣaaju, tabi lasiko iṣẹlẹ idaluru tabi iwa ọdaran to ba n waye laduugbo wọn.
Gẹgẹ bii atẹjade ti CSP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 1988, ni wọn gba obinrin yii sẹnu iṣẹ ọlọpaa.
Ọpọlọpọ iriri lo ti ni lẹnu iṣẹ naa lẹyin ti iṣẹ ti gbe e gba ọpọlọpọ ọfiisi kọja lawọn ipinlẹ bii Eko, Kano, Rivers ati Abuja ti i ṣe olu ilu ilẹ yii.
Bo ṣe jẹ pe CP Onadeko ni obinrin akọkọ to máa jẹ kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, bẹẹ ni ipinlẹ Ọyọ jẹ aaye akọkọ ti oun paapaa ti máa ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa, bo tilẹ jẹ pe lati ọdun 2019 lo ti gba agbega sipo CP, ṣugbọn to jẹ pe ànfààní ko tí ì ṣi silẹ fún un lati dá ṣakoso gbogbo awọn ọlọpaa odidi ipinlẹ kan.